Al-Shabaab gbẹsẹ le bọọlu gbigba lorilẹede Somalia

Ikọ alakatakiti Al-Shabaab gbe ibọn dani Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn olugbe ilu Mogadishu naa n bẹru awọn ikilọ ikọ Al-Shabaab

Iroyin n fidi rẹ mulẹ wi pe ẹgbẹ alakatakiti ẹsin ni, Al-shabaab ti ṣe ikilọ f'awọn eeyan orilẹede naa lati yago fun ere idaraya bọọlu gbigba o lawọn agbegbe kan ni olu ilu orilẹede naa, Mogadishu.

Nibayii ko din ni ogun papa isire to ti tẹle ikilọ yii

Gẹgẹ ohun ti awọn ileesẹ iroyin lorilẹede naa n sọ, awọn asiwaju ẹgbẹ alakatakiti Al-Shabaab se ipade pọ pẹlu awọn alakoso awọn papa isire kan lolu ilu orilẹede Somalia, Mogadishu.

Nibi ipade ọhun ni iroyin sọ wi pe ẹgbẹ alakatakiti naa ti tẹẹ mọ awọn to wa nibẹ leti wi pe ki gbogbo awọn papa isire aladani nibẹ lọ ti papa isire wọn pa ni kiakia.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ alakatakiti Al-Shabaab sepade pẹlu awọn alakoso papa isire nilu Mogadishu

Bi o tilẹ jẹ wi pe ko si ẹni to fẹ sọ ohunkohun lori ọrọ yii lati iha ijọba tabi awọn alakoso papa isire aladani ni orilẹede Somalia, sugbọn iroyin fi idi rẹ mulẹ wi peko si papa isire kan bayii ti wọn ti n gba bọọlu lorilẹede Somalia, bẹẹni ibẹru bojo ko jẹ ki awọn olugbe ilu Mogadishu.

Bakanaa ni iroyin ti sọ siwaju wi pe gbogbo awọn olugbe agbegbe mẹta ti ọrọ naa kan ni wọn gba ikilọ latọdọ ikọ alakatakiti Al-Shabaab pe wọn ko gbọdọ maa tan ina iwaju ile wọn silẹ ni alẹ mọ nitori o seese ki awọn ikọ naa o maa fẹ ki lilọ-bibọ wọn lalẹ o maa di mimọ.

Ni ọdun 2014, ikọ alakatakiti Al-Shabaab ṣe irufẹ ikilọ yii to rọ mọ ẹrọ ibanisọrọ alagbeka ti wọn kede nigba naa wi pe ko saye lilo ohun elo ayelujara nibẹ titi di akoko yii.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọ Al-Shabaab n gbimọran ati sefilọlẹ ijọba ẹsin Islam ni Somalia

Ikọ ọmọ ogun ijọba lo n sakoso ilu Mogadishu, sugbọn awọn olugbe ilu naa bẹru awọn ikilọ ikọ alakatakiti yii eyi ti wọn sọ wi pe o ni ọpọlọpọ alami laarin awọn eeyan ilu naa.

Ikọ alakatakiti Al-Shabaab n gbimọran ati sefilọlẹ ijọba ẹsin Islam lorilẹede Somalia lati kọ ipakọ si ohun gbogbo to ba rọ mọ ti oyinbo nibẹ.

Ọpọlọpọ eniyan ni wọn si ti pa lori ẹsun pe wọn n ba awọn ohun to nii se pẹlu oyinbo tabi ijọba orilẹede naa ti wọn n sọ wi pe o n ba oyinbo se pọ.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: