Awọn ọmọogun jẹwọ idi ti wọn ko fi lee pa ina Boko haram

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aisi iroyin to kuna n se akoba fun gbigbogun ti Boko Haram

Ileesẹ ọmọ ogun lorilẹede Naijiria ti jẹwọ ohun to faa ti o fi n mẹhẹ ninu pipese eto abo to pegede ati mimoke ninu gbigbogun ti awọn ikọ agbesunmọmi lorilẹẹede naa.

Illesẹ ọmọ ogun orilẹede Naijiria ni aisi iroyin to kuna nipa ogun ti wọn n dojukọ gan an lo fa a ti ina gbigbogun ti iwa idukukulaja fi n jo ajorẹyin.

Ninu ọrọ kan eleyi ti alukoro fun ileesẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria, Ọgagun John Agim ba BBC sọ, o ni aisi iroyin to to lati ọdọ awọn olugbe awọn agbegbe ti ina wahala naa ti n jo fun awọn ọmọogun n pagidina wiwa egbo dẹkun si gulegule awọn ikọ Boko Haram.

Ni ọsẹ meji meji sẹyin ni awọn ikọ Boko Haram ji awọn akẹkọbinrin to le ni ọgọrun gbe ni ileewe wọn to wa ni ilu Dapchi, ipinlẹ Yobe lẹkun ila orrun ariwa orilẹede Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọogun jẹwọ idi ti wọn ko fi lee pa ina Boko haram

Ohun ti iroyin sọ ni wi pe, wọn ko awọ ologun kuro lagbegbe naa ni nkan bii ọjọ diẹ saaju isẹlẹ naa.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: