Okei-Odumakin: Awọn obinrin Naijiria nilo ajọ iranwọ fun oṣelu'

Dokita okei-Odumakin Image copyright @DrJoeOdumakin
Àkọlé àwòrán O yẹ ki opin de ba lilo awọn obinrin gẹgẹbii ohun elo amuludun nikan

Bi awọn orilẹede agbaye ti ṣe n ṣe ayajọ ọjọ awọn obinrin, gbajugbaja ajafẹtọ kan lorilẹede Naijiria, Dokita Okey Okei-Odumakin ti ke gbare sita wi pe n kan o tii se ẹnure fun awọn obinrin lorilẹede Naijiria.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, Dokita okei-Odumakin ni asiko to fun awọn obinrin lati dide ja fun itẹsiwaju ara wọn bayii.

Odumakin ni awọn obinrin nilo ati pe fun idasilẹ asuwọn alajọni kan ti awọn obinrin lee maa ti inu rẹ mu owo lati ja fun ipo oṣelu.

Ajafẹtọ naa ni bi o tilẹ jẹ wi pe nkan ti n yi pada lori pipese eto ẹkọ fun awọn obinrin ṣugbọn aabo fun wọn si n mẹhẹ patapata.

Image copyright @DrJoeOdumakin
Àkọlé àwòrán 'Eredi ikọlu awọn agbebọn si awọn ile ẹkọ awọn akẹkọbinrin ni lati dawọn lẹkun lilọ si ileewe'

"Ajọṣepọ wa laarin eto abo ati eto ẹkọ nitori ẹni ti ko ba ni aabo to peye ko lee ronu ati lọ kẹkọ.

"O yẹ ki a kede akoko pajawiri lẹkun eto abo lorilẹede Naijiria.

"Bi a se n sọrọ yii, ọgọrun ninu awọn ọmọbinrin ti wọn ji gbe ni Chibok ni a si n wa, latun ri ti awọn ti Dapchi ti wọn ji gbe.

"Ijọba ni lati fi ipinnu han lori ipese abo ki wọn si yọ gbogbo awọn ti wọn ba rii wi pe wọn ko lee ṣiṣẹ ipese abo sita bi ẹni yọ jiga."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Odumakin: Naijiria ko gbọdọ ja awọn ọmọdebinrin naa kulẹ nipa ririi daju pe wọn ri wọn gba pada

O ni orilẹede Naijiria ko gbọdọ ja awọn ọmọdebinrin naa kulẹ nipa ririi daju pe wọn ri wọn gba pada.

Dokita Joe Okei-Odumakin ṣalaye wipe o yẹ ki opin de ba lilo awọn obinrin gẹgẹbii ohun elo amuludun nikan.

Gẹgẹbii ọrọ rẹ, igba ọdun ni awọn obinrin orilẹede Naijiria fi n rakoro lẹyin gbogbo iran yooku gẹgẹbii iwadi naa ti se sọ.

"Anfani ayajọ awọn obinrin yii ni lati woye awọn isẹ takuntakun ti awọn obinrin n se lagbaye.

"Ninu iwoye temi, isẹ si pọ fun awọn obinrin lati se ki wọn lee de ibi ẹkunrẹrẹ wọn."

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: