Charles Okah ati Obi Nwabueze gba'dajọ ẹwọn gbere

Charles Okah ati Obi Nwabueze gba'dajọ ẹwọn gbere

Ileẹjọ giga ijọba apapọ to kalẹ silu Abuja ti ran Charles Okah ati akẹẹgbẹ rẹ ti wọn dijọ njẹjọ, Obi Nwabueze ni ẹwọn gbere.

Wọn gba idajọ naa lori bi wọn sese agbatẹru ado oloro to bu nilu Abuja lọjọ kinni osu kẹwa ọdun 2010 ati nilu Warri lọjọ kẹẹdogun osu kẹta ọdun 2010 kannaa.

Awọn meejeji yii ni wọn gbinmọpọ pẹlu ẹgbọn Charles, Henry Okah, tii se asaaju ẹgbẹ to nja fun ominira awọn eeyan Biafra tijọba ti fofin de, (Mend) ẹni toun naa ti gba idajọ tiẹ lori ẹsun yii saaju lorilẹede South Africa.

Nigba to ngbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ naa to ti bẹrẹ lati ọjọ keje osu kejila ọdun 2010, adajọ Gabriel Kọlawọle ni awọn olupẹjọ fi idi ẹri wọn mulẹ kọja iyemeji.

Idi si ree to fi da ẹwọn gbere fun wọn nibamu pẹlu ofin to ngbogun ti iwa sise owo ilu basubasu ati iwa ọdaran tọdun 2004, ori kẹẹdogun, ẹsẹ kinni ati ikeji.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: