Tillerson: Owo yiya lọwọ orilẹede China lewu fun Afirika

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Ọgbẹni Rex Tillerson ati alaga ajọ isọkan Afirika n ki ara wọn Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede China ti di ọkan pataki laarin awọn orilẹede ti o ni ajọsepọ okoowo to pọ julọ ni ilẹ Afirika

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Ọgbẹni Rex Tillerson ti kilọ fun awọn ijọba orilẹede gbogbo ni ilẹ Afirika lati sọra fun yiya owo lọwọ orilẹede China.

Ọgbẹni Rex Tillerson sekilọ yii ni ilu Adidas ababa tii se olu ilu orilẹede Ethiopia, orilẹede akọkọ ti o kskọ gunlẹ si lẹnu abẹwo rẹ akọkọ si orilẹede Afirika.

Ọgbẹni Rex Tillerson ni owooya lati orilẹede China lewu pupọ fun awọn orilẹede Afirika ati wi pe ikilọ naa kii se ọgbọn ati di ọna mọ owo orilẹede China ti o n regun silẹ Afirika.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ọgbẹni Rex Tillerson ni ikilọ ti Amẹrika se kii se ọgbọn ati di ọna mọ owo orilẹede China ti o n regun silẹ Afirika

O ni ewu to wa ninu rẹ ni wi pe orilẹede to ba kuna lati san owo to ya pada lasiko lee padanu awọn ohun amayedẹrun gbogbo to na owo le lori.

Nigba ti wọn bii wi pe asiko to fun aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump lati tọrọ aforiji fun ọrọ kobakungbe to sọ nipa awọn orilẹede Afirika, Ọgbẹni Rex Tillerson ni ipinu orilẹede Amẹrika ni lati ni ajọsepọ to dan mọran pẹlu awọn orilẹede gbogbo ni ilẹ Afirika.

Bakannaa lo ni Aarẹ Donald Trum ti kọwe si alaga ajọ isọkan ilẹ Afrika lori ọrọ ọhun.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si:

Related Topics