Angelique kidjo ni asiko to fun idọgba laarin akọ ati abo

Gbajugbaja akọrin Angelique kidjo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Angelique Kidjo ni awọn obinrin lee da isẹ silẹ bi awọn ọkunrin ba fi aake kọri lori didọgba laarin an ọmọ ọkunrin ati obinrin

Gbajugbaja akọrin agbaye e ni, Angelique kidjo ti sọ wi pe o di igba ti awọn obi ba rii daju pe idọgba wa laarin ọmọ ọkunrin ati obinrin wọn ki wahala aidọgba laarin ẹya akọ ati abo to lee dopin ni ilẹ Afirika.

Angela Kidjo sọ ọrọ yii sita lasiko ifọrọwerọ to ba BBC ṣe lati sami ayajọ awọn obinrin lagbaye, akọrin gbayi ọmọ orilẹede Benin naa ni awọn obinrin ni lati yẹna ofin to duroore kalẹ lawọn idile wọn ki wọn lee dẹkun aye ẹru ati ọmọ ọdọ ti awọn ọmọ obinrin n gbe ninu ile ti yoo maa se ounjẹ fun awọn ọkunrin ni inu ile.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gbajugbaja akọrin Angelique kidjo pe fun anfani f'awọn obinrin

Angelique Kidjo, to jẹ asoju fun ajọ to n se amojuto idagbasoke awọn ọmọde labẹ ajọ isọkan agbaye sapejuwe awọn ọkunrin gẹgẹbii kiigbọ-kiigba ati pe nibi ti awọn ọkunrin ba ti fi aake kọri pe awọn ko ni gba, afi ki awọn obinrin naa yara gun le iyansẹlodi.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: