Naijiria sọkutu wọwọ l‘ayajọ awọn obinrin

Awọn obinrin ipinlẹ Ekiti nibi ajọyọ ayajọ awọn obinrin lagbaye Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Akori ajọyọ ayajọ awọn obinrin lagbaye fun ọ̀dun 2018 ni 'ja fun itẹsiwaju'

Bi ajọ agbaye ti se ya ọjọ kẹjọ osu kẹta sọtọ gẹgẹbii ayajọ awọn obinrin lagbaye, oniruuru ọrọ igbaniniyanju lo ti n jade fun awọn obinrin lorilẹede naijiria bi awọn naa se n darapọ mọ ajọyọ naa.

Aisha Buhari, iyawo aarẹ orilẹede Naijiria.

Image copyright @aishambuhari
Àkọlé àwòrán 'A n fi asiko yii ronu lori isẹlẹ ibanujẹ jiji awọn ọmọbinrin wa gbe, paapaa julọ ni Dapchi ipinlẹ Yobe'

"Loni, mo ki awọn obinrin orilẹede Naijiria ku oriire ayajọ awọn obinrin.

Fun wa lorilẹede Naijiria, iyatọ nla ni ajọyọ ayajọ yii ba de. A n fi asiko yii ronu lori isẹlẹ ibanujẹ jiji awọn ọmọbinrin wa gbe, paapaa julọ ni Dapchi ipinlẹ Yobe. Asiko ni yi fun wa lati bọ si gbangba. Idi ni yi ti a fi mu akori # LeaveOurDaughtersAlone (to tumọ si ẹ fi awọn ọmọ wa silẹ) lati pe fun fifopin si ajalu nla yii pẹlu ireti wi pe wọn yoo gba itusilẹ."

Atiku Abubakar, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria nigbakanri.

Image copyright @atiku
Àkọlé àwòrán 'Mo n ke si awọn ọkunrin, awọn baba, awọn olori ẹsin ati ọrọ oselu gbogbo lati parapọ hu iwa gẹgẹ bii eniyan lati mu ayipada rere ba igbe aye awọn obinrin'

"Loni ti a n se ayajọ awọn obinrin lagbaye, mo n ke si awọn ọkunrin, awọn baba, awọn olori ẹsin ati ọrọ oselu gbogbo lati para pọ hu iwa gẹgẹ bii eniyan lati mu ayipada rere ba igbe aye awọn obinrin."

Sẹnatọ Bukọla Saraki, Aarẹ ile asofin agba orilẹede Naijiria.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán 'Mo kan saara si awọn obinrin ti wọn ti ko ipa ribiribi ti wọn si tun si n ko ipa ribiribi ninu idagbasoke orilẹede wa-ni ẹka gbogbo'

"Loni, tii se ọjọ awọn obinrin lagbaye, mo ba awọn iya wa, aburo ati ẹgbọn wa lobinrin, awọn ọmọbinrin wa, ara ati ọrẹ lobinrin ti wọn n ji lojoojumọ lati rii wi pe ile aye dun un gbe fun tẹru tọmọ.

Mo kan saara si awọn obinrin ti wọn ti ko ipa ribiribi, ti wọn si tun si n ko ipa ribiribi ninu idagbasoke orilẹede wa ni ẹka gbogbo, ni ọna gbogbo ati ni gbogbo igba ninu itan wa."

Sẹnatọ Ike Ekweremadu, igbakeji aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán ' A ni lati maa kan sara si wọn fun isẹ takuntakun ti wọn n se ni ileesẹ ati ni ile'

" Ani lati maa fọnrere pataki awọn obinrin lojojumọ. A ni lati maa kan sara si wọn fun isẹ takuntakun ti wọn n se ni ileesẹ ati ninu ile. A n se koriya fun wọn lati tubọ maa du ipo asiwaju mu lorilẹede yii."

Bi a se nse ajọyọ yii, o se pataki ki awọn baba ati asiwaju wa gbogbo maa ranti lati rii pe awọn iya, iyawo ati awọn obinrin lapapọ n gba iyi to yẹ lai naani ipo tabi aaye ti wọn ba ara wọn."

Arẹgbẹsọla, Gomina ipinlẹ Ọsun, iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.

Image copyright @raufaregbesola
Àkọlé àwòrán 'A kan sara si awọn obinrin, awọn iyaa wa, iyawo wa, ẹgbọn ati aburo wa lobinrin fun itọju, ifẹ, iwa aforiti, ifarada, okun ati isedeede wọn'

"A kan sara si awọn obinrin, awọn iya wa, iyawo wa, ẹgbọn ati aburo wa lobinrin fun itọju, ifẹ, iwa aforiti, ifarada, okun ati isedeede wọn. Gbogbo obinrin lagbaye, mo ki yin loni ati lọjọ gbogbo."

Abiola Ajimọbi, gomina ipinlẹ Ọsun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.

Image copyright @AAAjimobi
Àkọlé àwòrán ' awọn olori wa lati tubọ maa rii daju wipe a fi ẹyẹ ọwọ ati iyi to yẹ fun awọn iya wa, iyawo wa ati gbogbo obinrin lapapọ'

Bi a se n se ajọyọ yii, o se pataki fun awọn baba wa ati awọn olori wa lati tubọ maa rii daju wipe a fi ẹyẹ, ọwọ ati iyi to yẹ fun awọn iya wa, iyawo wa ati gbogbo obinrin lapapọ ni ipokipo tabi aaye kaaye ti wọn ba wa.

Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Gomina Fayose gbe ori le iyawo rẹ lejika nibi ajọyọ ayajọ awọn obinrin lagbaye nilu Ado Ekiti
Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Iyawo gomina ipinlẹ Eko se ajọyọ ayajọ awọn obinrin lagbaye pẹlu awọn iyawo oloselu nilu Eko