Yobe: Obi awọn akẹkọ Dapchi nbeere ọmọ wọn

Awọn obi awọn akẹkọbinrin ti Boko Haram ji gbe lọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ obi awọn ọmọ ti Boko Haram ji gbe lo ti salaisi tabi se aarẹ

Awọn obi aadọfa akẹkọ ti ikọ adunkoko mọni Boko Haram ji gbe ni ọjọ mejidinlogun sẹyin ti ran asoju ransẹ silu Abuja lati beere fun idande awọn ọmọ wọn.

Akọwe ẹgbẹ obi ati olukọ nile iwe naa, Bakar Kachalla sọ fawọn akọroyin pe awọn asoju naa yoo kan sawọn ẹgbẹ to n polongo fun itusilẹ awọn akẹkọbinrin atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ obinrin nilu Abuja ti wọn pejọpọ fun ayajọ ọjọ obirin lagbaye lọjọbọ.

Kachalla ni igbagbọ awọn obi naa ni pe awọn ọmọ yii nkoju awọn iriri to buru jai idi si niyi tawọn fi gbọdọ se aayan lati sawari wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O ti ọjọ mejidinlogun bayi ti Boko Haram ti ji awọn akẹkọbinrin gbe lọ ni Dapchi

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

"Ọpọ awọn akẹkọ yii ni ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkanla si mẹẹdogun, ti wọn ko si da ọwọ ọtun yatọ mọ si tosi.O si seese ki iru iriri nla ti wọn ni lati igba ewe yii nipa lori igbe aye wọn lọjọ iwaju."

O wa nrọ ijọba apapọ lati tete kan si arabinrin Aisha Wakili, ti gbogbo eeyan mọ si Mama Boko Haram, ẹni to ti gburo ibiti awọn akẹkọ naa wa, ki wọn si dunadurapẹlu rẹ, lori bi wọn yoo se gba idande awọn akẹkọbinrin yii.