Aarẹ Buhari ṣ'eleri ati pese iṣẹ fun ọpọlọpọ

Aarẹ Buhari nipinlẹ Plateau Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ṣ'eleri iṣẹ fun ọpọlọpọ

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ijọba ṣetan ati tẹpẹlẹmo akiyantiyan lori pipese iṣẹ fun awọn ọdọ ọmọ orilẹede Naijiria.

Bakana lo ni ijoba yoo gbogun ti ebi oun iṣẹ pẹlu mumu itẹsiwaju ba iṣẹ-ọgbin.

Aarẹ Buhari sọ eyi ni ọjọbọ nibi ipade to ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ kan ni ilu Jos ni ọjọ kinni abẹwo ọlọjọ meji ti o n ṣe si ipinlẹ Plateau.

O ni "A ko le ṣẹgun ainiṣẹ ati ebi ti a ko ba jẹ ohun ti a gbe jade lati inu oko wa,"

"Lọpọ ipinle ti mo lo tofimọ Kano, Nasarawa ati Taraba, mo ri ọplọpọ ọdọ ti wọn ko ni iṣẹ lọwọ."

O gboriyin fun ijọba Plateau fun bi wọn ṣe gbaruku ti ilana ọgbin ijọba apapọ.

Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Buhari fẹ san owo ti ijọba ipinlẹ Plateau na nipasẹ awọn ọna ilu ti o jẹ ti ijọba apapọ

O so pe ijọba apapọ yoo san owo ti ijọba ipinlẹ Plateau na lori atunse oju ọna ti o jẹ ti ijọba apapọ.

Nigbati o n s'ọrọ lori awọn igbesẹ ijọba rẹ lati dẹkun iwa ibajẹ,Aarẹ Buhari sọ pe awọn eto ti wa ni pẹsẹ lati tun gba awọn ilẹ ti awọn oṣiṣẹ ijọba fi ọna ẹburu gba tẹlẹ.

Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ṣ'eleri pipese iṣẹ fun ọpọlọpọ

Gomina Simon Lalong ninu ọrọ tirẹ, sọ fun Aarẹ Buhari pe iṣakoso rẹ n lepa lati pese aabo ati iranlọwọ ti o peye fun awọn ara ilu.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: