Ijọba Ekiti ati alatako tahun sira wọn lori aworan ipolongo

Gomina Fayose Femi Ojudu ati Kayode Fayemi ninu ọkọ ofurufu Image copyright Facebook/Femi Ojudu
Àkọlé àwòrán Ofin o f'ayegba ki Gomina Fayose kopa ninu ibo to'n bọ lọna sugbọn ko daju pe yoo gbe lẹyin Femi Ojudu

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kilọ fun awọn ẹgbẹ oselu lati tọwọ ọmọ wọn b'asọ nipa lilẹ iwe ipolongo nilẹkulẹ tabi riri patako ipolongo si aaye to ba wuwọn paapa julọ ni ilu Ado Ekiti.

Lere Ọlayinka to jẹ agbẹnusọ fun Gomina Ayọdele Fayose lo sọ bẹẹ fun BBC.

Ọlayinka ni ofin to dena lilẹ patako ipolongo nilẹkulẹ ko jẹ tuntun ati wi pe igbese na ki se lati dunkukulaja mọ ọmọ ẹgbẹ oselu kankan bi ko se lati rii pe ohun gbogbo lọ leto leto.

Amọ o, awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti fesi pe ki ijọba mase fọwọ kan awọn patako ipolongo wọn.

Gboyega Adeoye to je alukoro fun ẹgbẹ atunbi ilẹ Ekiti, Ekiti Rebirth Organisation (ERO ) nigba ti o'n ba BBC Yoruba sọrọ ni lootọ ni wọn mu iwe wa fun awọn pe ki awọn san owo ki wọn to le ri patako ipolongo, sugbọn ''wọn o jẹ ki gbedeke ọjọ mẹrinla pe ki wọn to sofin lati maa wo patako wa''

Ọgbẹni Adeoye ni awọn setan lati tẹle ofin ipinlẹ naa sugbọn ko yẹ ki ijọba to wa nigboro ma dun kukulaja mọ araalu.

O tẹsiwaju pe awọn nsọ ibi ti awọn patako naa wa sugbọn ko tii si apẹrẹ pe ijọba yoo gbe igbesẹ lati wo patako ipolongo ti awọn gbe kalẹ.

Ibo Gomina nipinlẹ Ekiti, gẹgẹ bi ajọ eleto idibo se laa kalẹ, yoo waye ni ọjọ kẹrinla osu keje ọdun yi.