Ijọba Ondo wa ọdẹ to p'erin ni Idanre

Awon eeyan nwo erin ni India Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Pipa erin wopo ni ilu India naa

Ijọba ipinlẹ Ondo ti pariwo faraye wipe awọn n wa ọdẹ ti o yinbọn pa erin kan ninu igbo, ni ilu Idanre, loṣu to kọja.

Kọmiṣọna fun eto ohun alumọni ilẹ ni ipinlẹ Ondo, ọgbẹni Rasheed Badmus sọ fun ileeṣẹ BBC wipe ni kete ti ijọba ti gbọ ọrọ nipa erin ti wọn pa yii, ni ijọba ti gbe awọn ọlọpa, aṣọgbo ati awọn eleto aabo abẹle jade lati ṣe awari ọdẹ naa.

Iroyin f'idi rẹ mulẹ wipe ọdẹ yi na papa bo'ra lẹyin iṣẹlẹ yi to waye ninu aigbo ọba..

Ọgbẹni Badmus wipe iṣẹlẹ yi tako ofin ijọba ati eto aabo fun awọn ohun meremere ninu igbo ọba. O wipe ijiya t'o tọ wa fun ọlọdẹ naa, pẹlu alaye wipe ijọba ipinlẹ Ondo ti n ṣ'eto aabo t'o peye fun agbegbe naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Erin meji ni Masai Mara ni Kenya

Idanre jẹ ilu ti o lewaju ninu awọn ilu ti o n ṣe iṣẹ ọgbin cocoa ni orilẹede Naijiria, ṣugbọn awọn olugbe kan ni idanre sọ wipe awọn erin ti n pa awọn ere oko wọn lati ọjọ pipẹ.

Awọn alẹnulọrọ sọ wipe afurasi ọdẹ ti wọn pe ni Ajaja jẹ ẹni ti o ti pa erin miran ni ọdun mejila sẹyin.

Oriṣiriṣi awọn ọrọ lo ti n jade lori pipa erin yii lori awọn opo ayelujara Facebook ati Twitter to fi mọ instagram.

Laarin aṣa ati aabo ohun ini

Ninu iforowero pelu ileese BBC, Desmond Majekodunmi, onimọ nipa eeto idaabo bo awọn ohun ini ati alumọni ile kedun wipe ohun ti oburu jai ni isele yi.

Ọgbẹni Majekodunmi wipe ijọba gbodo pese eeto aabo to peye fun awon aginju gbogbo ti won wa fun titoju awon eranko meremere ni orileede Naijiria.

O bu enu ete lu ipa ti asa ti ise Yoruba nko nipa gbigboriyin fun ode aperin laye atijo, eyi ti o sapejuwe gegebi ohun atijo ti ko bojumu ati eyi ti o lodi sofin igbalode.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: