Aarẹ Kenyatta ṣe'pade pẹlu olori alatako, Odinga

Aarẹ Uhuru Kenyatta ati Raila Odinga Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ ni yi ti Kenyatta ati Odinga yoo maa pade lẹyin idibo apapọ lorilẹede Kenya

Ọrọ n sebi ẹni fẹ ba ibomiran yọ bayii lorilede Kenya nibiti aarẹ orilẹede naa, Uhuru Kenyatta ti n joko sọrọ bayii pẹlu asaaju alatako rẹ, Raila Odinga.

Olu ilu orilẹede Kenya, Nairobi ni ipade yii ti n waye.

Pataki lara awọn alatako Kenyatta ni Odinga jẹ, koda ni ibẹrẹ ọdun 2018 ni Odinga se ijẹjẹ fun ara rẹ gẹgẹbii aarẹ orilẹede Kenya leyin wọlukọlu to waye nibi idibo apapọ nibẹ.

Eyi si ni ipade akọkọ laarin awọn oloselu mejeeji yii ni gbangba lẹyin igba naa.

Lẹyin ti awọn adari mejeeji sepade, aarẹ Kenyatta nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, pe fun ifọwọsowọpọ laarin awọn ọmọ ilẹ Kenya fun idagbasoke orilẹede naa.

Ninu ọrọ tirẹ, Odinga pe fun ẹyọnu awọn eniyan lati se aforiji fun ara wọn, ki wọn si jẹ ki alaafia o jọba laarin awọn ọmọ ile naa, gẹgẹbi o se pe aarẹ Kenyatta ni ibatan oun.

Ipade awọn oloselu mejeeji yii waye lasiko abẹwo Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson gunlẹ si orilẹede naa fun abẹwo ọlọjọ mẹrin.

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ sọwipe ko din ni aadọjọ eeyan to ku lasiko hilahilo to waye lẹyin idibo apapọ lorilẹede naa lọdun to kọja.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: