Tever Akase: Ipinlẹ Benue ko fa'gile eto isinku gbogboogbo

Eto isinku apapo fun awon to ku ninu ikolu losu kini odun yi nipinle Benue

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipinle Benue ni ikolu to buru ju losu kini odun yi

Ijọba ipinlẹ Benue wipe awọn ko fagile isinku gbogboogbo ti wọn pin nu lati ṣe fun awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu awọn darandaran Fulani ni agbẹgbẹ Okpokwu.

Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom nigba to ṣayewo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti o waye lagbeegbe Omusu Edimoga, ni ijọba ibilẹ Okpokwu, ṣe'leri wipe ijọba ipinlẹ naa yoo ṣe isinku gbogbogbo fun eniyan mẹrinlelogun to padanu ẹmi wọn naa.

Ṣugbọn iroyin tan kaakiri wipe ijọba ipinlẹ naa ti wọgile eto isinku yii, nitori igaradi lati gba'lejo olori orilẹede Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ aje to nbọ.

Amọ, alukoro fun gomina ipinlẹ Benue,Terver Akase ninu ipe rẹ si ileeṣẹ BBC sọ pe irọ nla patapata ni eyi ati wipe ijọba ko nipa lati ṣe eto isinku naa ni ọjọ ẹti.

O wipe oun ko fi atẹjade kankan ṣọwọ sawọn oniroyin nipa fifagile isinku gbogboogbo naa.

O fi idi rẹ mulẹ wipe eto isinku naa yoo waye ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹta.

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipaniya lẹnu ọjọ mẹta yi ni Benue ti sọ ọpọ sinu ibanujẹ

Iroyin sọwipe awọn darandaran naa ṣe ikọlu si agbeegbe naa ni bii agogo meji si mẹta ọsan ọjọ naa, lẹyin ti wọn fẹsun kan awọn ara abule naa wipe wọn ji maalu wọn gbe.

Iroyin naa fi kun wipe, awọn ọmọde wa ninu awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa, ti ọpọlọpọ si f'arapa.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: