Ọwọ tẹ agbofinro meji lori iṣowo ọmọniyan

Awọn onjafẹtọ ọmọniyan n ke gbajare wipe isowo ọmọniyan to gẹẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O sọwọn ki wọn ba awọn agbofinro nibi isowo ọmọniyan

Ileeṣẹ to n mojutọ iṣiwa ati iṣilọ ni Naijiria ti bẹrẹẹ iwadi lori awọn oṣiṣẹ rẹ meji kan ti wọn furasi wipe wọn fẹ ko awọn ọmọbirin jade kuro ni Naijiria lọna aitọ.

Ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọbirin ni wọn maa n ko jade kuro ni orilẹede Naijiria to ni eeyan julọ nilẹ Afrika lọdọdun.

Awọn kan ninu awọn ọmọbirin naa maa n de si ilẹ Yuroopu nigba ti awọn ọmiraa maa n ha mọ orilẹede Libya.

Agbẹnusọ fun ileeṣe iṣiwa ati iṣilọ Naijiria, Sunday James, sọ fun ileeṣe iroyin Reuters wipe: " a gbọ wipe ọwọ tẹ awọn oṣiṣẹ wa meji kan ni papa ọkọ ofurufu to wa l'Eko nigba ti wọn gbiyanju lati ko awọn ọmọbirin kekeke kan jade lọna aitọ.

"Wọn ti fi ọrọ na to ọga ileeṣẹ iṣiwa ati iṣilọ Naijiria leti, a si ti bẹrẹ iwadi lori rẹ."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Papa ọkọ ofurufu to wa l'Eko