Atipo Naijiria 50 rigbala kuro ninu odo Libya

Ọpọ ninu awọn atipo naa jẹ ọmọ Naijiria Image copyright Twitter/@nicolacois
Àkọlé àwòrán Ọpọ ninu awọn atipo naa jẹ ọmọ Naijiria

Wọn ti gba adọta atipo Naijiria laa ninu odo Libya.

Awọn atipo naa wa ninu adọfa eeyan ti wọn gba sile lati inu ọkọ ojuomi kekere kan ti wọn fe lo lati wọ Yuroopu lọna aitọ.

Ileeṣẹ iroyin Reuters sọ wipe awọn ọmọ Naijiri le nidaji awọn atipo to wa ninu ọkọjuomi naa.

Awọn ọmọ Naijiria ati awọn awọn ọmọ orilẹede adulawọ miran pupọ ti padanu ẹmi ati ominira wọn lori igbiyanju lati gba Libya lọ si Yuroopu lọna aitọ.