Ẹgbẹ APC lo le waju esi ibo Sierra Leone

Eeyan bi miliọnu mẹta ni wọn ro wipe wọn dibo Sierra Leone lọdun yii Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eeyan bi miliọnu mẹta ni wọn ro wipe wọn dibo Sierra Leone lọdun yii

Ajọ to n s'eto ibo lorilẹede Sierra Leone ti kede idaji ninu esi ibo aarẹ orilẹede naa ti wọn di l'Ọjọru (Wednesday).

Idaji esi ibo ti wọn gbe jade fi han wipe ẹgbẹ oselu APC to n ṣe ijọba lorilẹede naa lo wa ni waju.

Alaga ajọ naa, Ọgbẹni Mohammed Nfah Conteh, bun awọn ọmọ orilẹede naa ni suuru nitori wipe ajọ rẹ ko tete kede esi ibo naa.

O sọ wipe: "Ọgbẹni Kamara ti ẹgbẹ oselu All Peoples Congress (APC) ti ni to ibo 566, 113, bayii ati wipe Ọgbẹni Bio Julius Maada ti ni to ibo 564, 687.

"Eleyi ni idaji esi ibo ti wọn di ti ajọ to n s'eto idibo ni aridaju pe ogidi ibo ni. Esi idaji ibo ti wọn di ni eleyii, nitorina eleyi kii ṣe ẹkunrẹrẹ esi ibo."