Ẹmi mẹrin ṣ'ofo, mẹrindinlogun f'arapa ninu ijamba ọkọ ni Lekki

Ọkọ danfo ti o ni ikọlu Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Ọkọ danfo yii ati ọkọ jiipu kan ni wọn kọlu arawọn

Ileeṣẹ ti o n risi iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko (Lasema) ti fidirẹ mulẹ wipe eniyan mẹrin ni o padanu ẹmi wọn ti awọn bi mẹrindinlogun miran si f'arapa yanayana nilu ijamba ọkọ ti o ṣẹlẹ ni opopona marosẹ Lekki/Epe lọjọ aiku.

Adari agba fun illeeṣẹ naa, ọgbẹni Adesina Tiamiyu ninu atẹjade kan salaye wipe ijamba yi waye ni itosi ile igbafẹ Oriental.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Ijamba yi waye ni itosi ile igbafẹ Oriental

Ọgbẹni Tiamiyu ṣalaye wipe ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kan ṣa deede ya si opopona awọn eniyan miran ti o si kọlu ọkọ akero kan ti o ṣẹṣẹ n kuro ni ẹnu ibode Lekki.

O fi kun un wipe ọkunrin mẹta ati obinrin kan ni awọn ti o j'ọlọrun nipe lẹsẹkẹsẹ, ti awọn obinrin mẹrin ati ọkunrin mejila miran si ti wa ni ile iwosan ti ijọba ni Marina.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Eniyan mẹrin ni o padanu ẹmi wọn

Ileeṣẹ Laema wipe awọn ti palẹ mọ ibi ti ijamba ọkọ naa ti ṣẹlẹ.

Ẹnikan ninu awọn to wọ ọkọ danfo naa sọ wipe lati Ikate l'oun ti wọ ọkọ naa.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Awon to farakaaṣa ti ngbawosan bayi

O fi kun un wipe wọn ti wo oun ni ile-iwosan ti wọn gbe oun lọ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: