Yahaya Bello ni oun ko tu igbimọ iṣejọba ipinlẹ Kogi ka

Yahaya Bello Image copyright @FanwoKings
Àkọlé àwòrán Digbi n'ijọba Kogi wa - Yahaya Bello

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello wipe oun ko f'igba kan kan yọ awọn kọmiṣọna ati awọn alaga ibilẹ nipo nipinlẹ naa.

Agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Kogi, Fanwo Kingsley sọ fun ileeṣẹ BBC wi pe ko si otitọ ninu ọrọ ti awọn oniroyin nsọ nipa ijọba ipinlẹ naa.

O wi pe gomina Bello ko tii da awọn kọmiṣọna ati awọn alaga ibilẹ duro lẹnu iṣẹ, ati wi pe ẹni ti wọn ba da duro kọ ni wọn maa n pe pada s'ẹnu iṣẹ.

Ọgbẹni Bello ti kọkọ kede idaduro lẹnu iṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ mẹẹdogun ati awọn alaga ibilẹ mọkanlelogun ninu ipade kan pẹlu awọn oloṣelu ni ileeṣẹ ijọba ni ilu Lọkọja lọjọ aiku.

Laipẹ ti iroyin yii jade ni iroyin miran tun gbode kan wi pe Gomina Bello ti yi ohun rẹ pada, ti o si ti pe awọn ti o da duro pada sẹnu iṣẹ wọn.

Agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ Kogi, Fanwo Kingsley bu ẹnu atẹ lu iroyin naa, o salaye pe irọ patapata ni.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: