Buhari, Minisita f'ọrọ okeere nilẹ Amẹrika, Tillerson n ṣe'pade lọwọ

Aare Buhari ati Ọgbẹni Rex Tillerson Image copyright STATE HOUSE
Àkọlé àwòrán Tillerson wa lẹnu abẹwo rẹ akọkọ si ilẹ Afirika

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Ọgbẹni Rex Tillerson yoo lo n se ipade lọwọ pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lnile ijọba.

Ipade na bẹrẹ ni kete ti Aarẹ Buhari dari lati abẹwo rẹ si ipinlẹ Benue.

Bashir Ahmad oluranlowo si Aare lori ibanisọrọ ayẹlujara lo fi iroyin lede loju opo twita re.

Image copyright STATE HOUSE
Àkọlé àwòrán Ọgbẹni Rex Tillerson ti de ni Ethiopia, Kenya ati Chad

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson ti wa lẹnu abẹwo si ilẹ Afirika lati bi ọsẹ kan sẹyin.

Lara awọn orilẹede ti Ọgbẹni Rex Tillerson ti de ni Ethiopia, Kenya ati Chad.

Image copyright STATE HOUSE
Àkọlé àwòrán Ọgbẹni Rex Tillerson n pada si America lojo isegun

Ileeṣẹ iroyin Reuters wi pe ọgbẹni Rex Tillerson nge abẹwo rẹ kuru si ilẹ Africa ti yoo si pada si Washington DC ni ọjọ iṣẹgun.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: