Orthom: Buhari mọ awọn to n damu ipinlẹ Benue

Buhari n gba ododo ikin kaabọ lọwọ ọmọdebinrin kan nigbati Gomina Orthom n wo o pẹlu ẹrin Image copyright benue_state_government
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba akọkọti aarẹ Buhari yoo de ipinlẹ Benue lati igba ti gulegule ikọlu awọn darndarn fulani ti bẹrẹ nibẹ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pari abẹwo ọlọjọ kan to se si ipinlẹ Benue lati sepade pẹlawọn eeyan ipinlẹ naa lori awọn ikọlu to n fi ojojumọ waye nibẹ.

Gẹgẹbi iroyin se sọ, abẹwo naa fun gomina Samuel Ortom ti ipinlẹ Benue atawọn asiwaju igun ẹgbẹ, ẹsin ati ẹya gbogbo nipinlẹ naa laaye lati sọrọ ni san-an fun aarẹ.

Ninu ọrọ rẹ, gẹgẹbii agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Benue, ọgbẹni Tever Akase se sọ, Gomina Ortom salaye fun Aarẹ Buhari wi pe inu awọn eeyan ipinlẹ naa ko dun pẹlu aarẹ pẹlu ọwọ to fi mu ikọlu ati ipaniyan to n waye ni ipinlẹ naa.

Gomina Orthom ni bi o tilẹ jẹ wi pe ireti awọn eeyan ni wi pe idasilẹ ikọ ọmọogun kogberegbe ti o fi ransẹ̀ sibẹ laipẹ yii yoo fun wọn ni abo to tọ sugbọn ọrọ ko ri bi wọn se ro mọ.

Kini otitọ ti awọn olukopa ba aarẹ Buhari sọ?

Saaju ipade yii ni awọn eeyan ti woye wi pe anfani nla ni yoo jẹ fun gbogbo awọn alẹnulọrọ ni ipinlẹ Benue lati ṣifọn leekanna fun aarẹ lori bi o se n seto aabo nibẹ.

Gbogbo ohun to rọ mọ rogbodiyan laarin awọn agbẹ oloko ati awọn darandaran fulani ni gomina Samuel Ortom yanana fun aarẹ nibi ipade naa.

Gẹgẹbi ohun ti ọgbẹni Akase sọ fun BBC Yoruba, "Gomina Orthom ke si aarẹ lati pasẹ fawọn agbofinro wi pe ki wọn gbe awọn asaaju ẹgbẹ Miyetti Allah Kautal hore ti o ti n lewaju 'dana ogun, dana ọtẹ' ni ipinlẹ naa. Ẹgbẹ ti n dun mọhuru mọ awọn eeyan ipinlẹ Benue lati igba ti ofin majẹko ni gbangba ti bẹrẹ ni ipinlẹ naa."

"Gomina Orthom sọọ yanya fun aarẹ Buhari wi pe o mọ awọn to n damu ipinlẹ Benue sugbọn ko fẹ sọ oju abẹ niko ni. Bi aarẹ ba lee fi awọn eeyan wọnyi jofin, o di dandan ki awọn eeyan wọnyii ti ọwọ ọmọ wọn bọ asọ."

Itẹwọgba Buhari ni abẹwo rẹ Opopona da paroparo lasiko abẹwo aarẹ

Image copyright @ogundamisi
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ko jẹ ki aidunnu ọkan awọn eeyan ipinlẹ Benue da omi tutu sii lọkan lasiko abẹwo rẹ

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe n se ni awọn opopona ni ilu Makurdi tii se olu ilu ipinlẹ Benue da paroparo lasiko abẹwo aarẹ si ipinlẹ naa.

Ọpọ onwoye lo woo wi pe, eyi lee jẹ afihan aidun ọkan awọn eeyan ipinlẹ Benue si ọwọ ti aarẹ fi mu ikọlu awọn darandaran fulani ni ipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ Benue ni eyi ko daju boya afihan aidunu awọn eeyan ipinlẹ naa ni.

"Kii se abẹwo ẹnu isẹ ni aarẹ se, idi niyi ti a ko fi see ni alariwo." Bi o tilẹ jẹ wi pe abẹwo aarẹ si awọn ipinlẹ kan saaju Benue ko sai ni tilu-tifọn ninu.

"Awọn eeyan Benue ko lee yọnu si Buhari ayafi..."

Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Aarẹ Seleri wi pe igbesẹ to tọ yoo maa waye lati daabo bo ẹmi gbogbo eeyan lorilẹede Naijiria

" Ko di igba ti a ba wi fun aarẹ ki o to mọ wi pe inu awọn eeyan ipinlẹ yii ko dun si ohun."

Gẹgẹbi ijọba ipinlẹ Benue ti se sọ, awọn eeyan ipinlẹ Benue ko fi igba kan fi ẹdun ọkan wọn pamọ lori bi aarẹ se n se lori ọrọ abo nibẹ.

"Mi o le sọ pe ohun to farahan niyi loni lasiko abẹwo aarẹ sugbọn ohun kan to daju ni wi pe, o digba ti aarẹ ba fi han wi pe oun ni ipinnu lati dojukọ ikọlu yii ki araalu to lee sọ wi pe awọn yọnu sii.

Aarẹ Buhari ṣi lanfani lati tun ọmọluwabi rẹ se lọdọ awọn eeyan ipinlẹ Benue atawọn ipinlẹ yooku ti ikọlu ati ipaniyan ti n waye."

Kini aarẹ sọ fun ipinlẹ Benue?

Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Gbogbo ohun to rọ mọ rogbodiyan laarin awọn agbẹ oloko ati awọn darandaran fulani ni wọnyanana fun aarẹ nibi ipade naa

Aarẹ Buhari ko jẹ ki aidunnu ọkan awọn eeyan ipinlẹ Benue da omi tutu sii lọkan.

Aarẹ seleri wi pe igbesẹ to tọ yoo maa waye lati daabo bo ẹmi gbogbo eeyan lorilẹede Naijiria lai naani ibi yoowu ti wọn ti le wa.

"A ko ni fi aye gba ẹnikẹni to ba gba ẹmi lati sa lọ mọ ofin lọwọ.

Gbogbo awọn ileesẹ aabo lati fun lasẹ lati sisẹ fun idaabo bo awọn ọmọ orilẹede yii.

"Mi o le se aarẹ titi aye, bẹẹni Gomina Ortom ko le wa ni ipo gomina titi ayeraye. Lẹyin isejọba wa, awọn agbẹ oloko ati darandaran ni ipinlẹ Benue ati nibikibi lorerilẹede Naijiria, yoo si maa ba ara wọn gbe pọ ireti wa ni wi pe ibagbepọ wọn yoo nmu alaafia dani."