Ijọba Ghana paṣẹ ki awọn oniṣowo ṣidi kuro niwaju ile Aarẹ

Aworan Aare Ghana Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ero s'ọtọtọ lori igbese yi lorilẹẹde Ghana

Wọn ti paṣẹ ki awọn oniṣowo ati o'ntaja ti isọ wọn kọju si ile Aarẹ orilẹede Ghana lati ṣidi kuro nibẹ ni kiakia.

Awọn ti ile wọn wa ni adojukọ ile Aarẹ ati awọn ti wọn ntaja ni agbegbe rẹ ni wọn ti fun ni gbedeke titi di Ọjọbọ lati palẹ ẹru wọn mọ latari bi ijọba ti ṣe sọ ibẹ di ilẹ ọwọ.

Ọrọ naa ko tu irun lara diẹ lara awọn ara adugbo ati awọn ti wọn ni ile itaja nibẹ, ṣugbọn niṣe ni ẹru'n ba awọn kan ti wọn ko mọ ibi ori n gbe wọn lọ.

Joseph Kobina, to ti'n gbe adugbo naa lati nnkan bi ọgbọn ọdun sọ fun ile iṣẹ iroyin Citi News ti orilẹẹde Ghana pe "Bi mo ba ti ẹ ri aye miran ko lọ, owo ti wọn fun wa ko le to ṣe nkankan.

"Ko le gba ibugbe mi fun mi...

''O yẹ ki wọn fi kun gbedeke naa, o si yẹ ki wọn fikun iye owo gba ma binu ti wọn fẹẹ fun wa nitori pe ẹgbẹrun mẹta Cedi ko le to ṣe nkankan.''

Oniroyin wa, Akwasi Sarpong ni igbesẹ yi ti mu ki ero ṣe ọtọọto laarin awọn ọmọ orilẹede Ghana.

O jabọ lati ẹnu ara ilu fun BBC Africa Live pe bi awọn eniyan ti ṣe'n patẹ soju ọna, ti awọn kan si n sun sibi ti wọn ri jẹ ohun ti ọkan kọ.

Ṣugbọn wọn ni bi ile iṣẹ aabo ti ṣe paṣẹ kiwọn ko ẹru wọn kuro jẹ iwa alailaanu.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics