Naijiria fẹ joko sọrọ pẹlu Boko Haram fun itusilẹ akẹkọ Dapchi

Tillerson ati Buhari Image copyright TWITTER /NIGERIAN PRESIDENCY
Àkọlé àwòrán Abẹwo akọwe agba Tillerson si Buhari lo kase irinaajo rẹ si ile Afrika

Ijọba orilẹẹde Naijiria ni oun yoo se amulo idunadura lati doola ẹmi awọn aadọfa akẹkọ lati ilu Dapchi dipo lilo ọmọogun.

Ikọ Boko Haram ji awọn ọmọ obirin naa gbe ni ileẹkọ wọn to wa ni iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria losu to kọja.

Ninu atẹjade kan ti ileesẹ aarẹ orilẹede Naijiria fi sọwọ lẹyin ipade pẹlu minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, ọgbẹni Rex Tillerson, Aare Muhammadu Buhari ni ijọba n sisẹ pẹlu awọn ajọ agbaye ati awọn onidunadura lati rii wi pe wọn da awọn akẹkọ naa pada lalaafia.

Lẹyin ipade pẹlu Aarẹ Buhari, minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson tẹnumọ ipinu orilẹẹde Amẹrika lati se iranlọwọ to ba yẹ fun orilẹede Naijiria.