Miliọnu meje kaadi idibo lajọ Inec yoo bajẹ ṣaaju ibo 2019

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionINEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, Inec ni afaimọ ki awọn maa wa nkan se si obitibiti kaadi idibo ti awọn oludibo to f'orukọ silẹ ko tii wa gba kaakiri awọn ileeṣẹ ajọ naa lorilẹede Naijiria.

Alaga ajọ naa ni ipinlẹ Ondo, Ọmọwe Rufus Akẹju lo kọkọ ṣ'alaye ọrọ yii fun awọn oniroyin nilu Akurẹ ki Kọmisọna apapọ fun eto idanilẹkọ ati ipolongo lajọ Inec, Ọgbẹni Deji Shoyebi to fidi rẹ mulẹ fun BBC wi pe igbesẹ yii ti di dandan ki o too di akoko ibo apapọ ti o nbọ.

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Awọn ẹgbẹ oselu ni ki ajọ INEC o ma se e ni warawara

Ọgbẹni Shoyebi ni ajọ Inec ko tii sọ igba kan ni pato ti yoo wa nkan se si awọn kaadi naa.

"A o sọ wi pe a maa sun un nina naa bẹyẹn ṣugbọn o yẹ ki ẹ mọ wi pe a ko lee tọju awọn kaadi yẹn lai wa nkan ti a maa se si wọn.

"Wọn ti n lo ọdun mẹta, ọdun mẹrin lọ lai si nkan ti a maa se si wọn.

"To ba ya ti a ko ba ri awọn to maa gba a, a maa wa nkan se si wọn, bo jẹ pe ka da wọn pada si ibi ti wọn ti ṣe e ki wọn tun wọn mọ fun omiran, sugbọn nkan ti a sọ ni wi pe a ko lee tọju awọn kaadi idibo yii pẹ julọ."

  • Aadọrin milliọnu ni kaadi idibo ti ajọ Inec ti tẹ sita
  • Miliọnu mẹtalelọgọta kaadi ni awọn oludibo si gba lọwọ ajọ Inec
  • Miliọnu meje kaadi oludibo, to duro ida mẹwa kaadi ti ajọ Inec tẹ jade ni wọn ko tii ri eeyan wa gba bayii
  • Bi ọrọ ko ba yi pada, o ṣeeṣe ki miliọnu meje eeyan maa lee dibo lọdun 2019.

Ọgbẹni Soyebi ni o le ni ọgọta miliọnu kaadi idibo ti wọn ti sita ṣugbọn awọn kaadi bii miliọnu meje miran ni wọn ko tii ri eeyan wa gba.

Ninu ọrọ ti wọn awọn ẹgbẹ oṣelu ti sọ wi pe ko si ohun to buru ninu igbesẹ ti ajọ naa fẹ gbe ṣugbọn ki wọn ṣee ni pẹsẹpẹsẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ẹgbẹ oselu nilo lati da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lẹkọ lori pataki gbigba kaadi idibo

Kini iha ẹgbẹ oṣelu sii?

Igbakeji alukoro apapọ fun ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Diran Ọdẹyẹmi, ni irufẹ igbesẹ bẹẹ lee waye lẹyin ti ajọ naa ba ti se ipolongo to kuna lori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionINEC yoo dana sun miliọnu meje kaadi idibo

"Ki wọn maa se ni wiriwiri bayẹn sugbọn bi awọn eeyan ko ba wa gba ni ọjọ ti wọn ba fi si, a fọwọ sii ki wọn jo nitori bi wọn ko ba jo awọn kọlọransi lee lo lati fi seru ibo. ẹni ti oju rẹ o si nibẹ ki wọn maa lọ ha le wọn lọwọ. Ki wọn maa lọ haa le awọn ọmọ kekeeke lọwọ lati se eru ibo."

Kọmisọna apapọ fun eto idanilẹkọ ati ipolongo lajọ Inec, Ọgbẹni Adedeji Shoyebi tun salaye wi pe kudiẹ kudiẹ to n waye lori eto iforukọsilẹ oludibo ti o n lọ lọwọ ko se lẹyin bi awọn ẹrọ iforukọsilẹ to wa ni ikawọ ajọ Inec ko se pọ to nitori aisi owo.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: