Ẹgbẹrun kan ẹjọ ni Inec ti se lori idibo 2015

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹrun kan ẹjọ ni Inec ti se lori idibo 2015

Ko din ni ẹgbẹrun kan ipẹjọ ti ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti la kọja laarin ọdun 2015 ti eto idibo apapọ orilẹede Naijiria waye si asiko yii.

Alaga apapọ ajọ Inec, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lo kede eyi nilu Abuja.

Ọjọgbọn Yakubu ni eyi jẹ ara ipenija ti ajọ naa n ba finra lọna ati se ilana idibo to duro deede fun orilẹede Naijiria.

Nibi ijoko itagbangba lori idasilẹ ajọ ti yoo maa mojuto awọn iwa aitọ to ba rọ mọ ọrọ ibo eyi ti awọn asofin agba lorilẹede Naijiria bẹrẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọgbọn Yakubu ni eyi jẹ ara ipenija ti ajọ naa n ba finra lọna ati se ilana idibo

"Ọkan o jọkan awọn ipẹjọ latọdọ awọn ọlọpa ni a ti gbe yẹwo, lẹyin o rẹ yin ọgọjọ awọn eeyan to sẹ si ofin eto idibo lati fi jofin.

Ofin yii yoo tubọ fi idi ajọ Inec mulẹ daadaa ni."

Ninu ọrọ rẹ asofin agba Ibn Na'Allah ni ominu n kọ awọn asofin agba wi pe o seese ki ajọ naa o fi ayekaye silẹ fun awọn ẹgbẹ oselu kan lati maa se ohun to wu wọn saaju akoko idibo.

Awọn asiwaju ileesẹ alaabo gbogbo to wa nibi ipade naa ni wọn salaye wi pe akoko ti to fun idasilẹ ajọ ti yoo maa mojuto awọn iwa aitọ to ba rọ mọ ọrọ ibo lorilẹede Naijiria lati mu ilana tootọ ba ẹka etovidibo lorilẹede Naijiria.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: