Kini ero ara ilu lori miliọnu mẹtala abọ naira ti awọn sẹnatọ Naijiria gba?

Awọn sẹnatọ orilẹede Naijiria nibi ijoko ile Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Sani Shehu lo tu ewe lara ẹkọ owo ti awọn sẹnatọ orilẹede Naijiria n gba laipẹ yii

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n fi ehonu wọn han lori owo miliọnu mẹtala abọ naira ti awọn aṣofin agba orilẹede Naijiria n gba.

Lara awọn ti wọn ba BBC Yoruba s'ọrọ wipe ohun iyalẹnu ni o jẹ pe awọn aṣofin n gba owo gọbọi bayi, eyi kii tun ṣe owo oṣu wọn.

Sugbọn ileegbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe ko si ohun tuntun kan ninu miliọnu mẹtala abọ naira ti sẹnatọ Shehu Sani kede wi pe awọn n mu rele loṣooṣu yatọ si owo oṣu wọn gan an ni san an.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEro ara ilu lori owo awọn sẹnatọ Naijiria

Agbẹnusọ fun ile aṣofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnatọ Aliyu Sabi Abdullahi tun fi ẹyin ọwọ gba iroyin ti o nja ranyinranyin kaakiri wi pe awọn asofin agba yoku ti n kanra mọ Sẹnatọ Sani wi pe o tu asiri wọn faraalu.

Sẹnatọ Abdullahi ni ibasepe awọn araalu ti farabalẹ wo iwe eto isuna ile asofin naa ni, yoo ti han gbangba si wọn wi pe awọn owoona fun irinajo, itọju aisan ati bẹẹbẹẹlọ wa labẹ eto isuna ile naa, eyi si ni wọn pin fun awọn asofin naa.

Ipo Owo osu lọdun Apapọ ajẹmọnu lọdun Apapọ ajẹmọnu losu
Aarẹ 3,514,705.00 (Miliọnu mẹta abọ naira o le diẹ) 14,058,820.00 1,171,568.33
Igbakeji Aarẹ 3,051,572.50 12,126,290.00 1,010,524.17
Aarẹ Ile asofin agba 2,484,240.50 8,694,848.75 724,570.73
Igbakeji aarẹ Ile asofin agba 2,309,166.75 8,082,083.63 673,506.97
Sẹnatọ kọọkan 2,026,400.00 12,766,320.00 1,06,860.00
Olori ile asofinsoju 2,477,110.00 4,954,200.00 412,851.67
Igbakeji olori ile asofinsoju 2,287,034.25 4,574,068.50 381,172.38
Ọmọ ile asofinsoju 1,985,212.50 9,529,020.00 794,085.00

Lati ọdọ: Ajọ to n pin owo ilu lorilẹ̀ede Naijiria, RMAFC, http://www.rmafc.gov.ng/

''Gbogbo awọn to di ipo oselu mu ni wọn ni owo ti wọn fi n se amojuto aaye wọn, ko si si ẹni ti yoo wa pe irufẹ owo bẹẹ ni owo osu wọn."

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹrun mejidinlogun lowo osu osisẹ to kereju ni Naijiria, awọn ẹgbẹ osisẹ si n ja fun afikun owo yii

Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Sẹnatọ Shehu Sani ti o n soju ẹkun idibo apapọ kan ni ipinlẹ Kaduna tu ew lara ọrọ owo osu awọn asofin apapọ lorilẹede Naijiria nipa kikede rẹ wi pe yatọ si owo osu, ọkọọkan awọn asofin agba lorilẹede Naijiria lo n gba miliọnu mẹtala abọ losu.

Ipo orilẹede kọọkan Orilẹede Owo ti wọn n gba lọdun (Miliọnu Naira)
Ekini Nigeria 29.8(Ọgbọn miliọnu naira din diẹ)
Ekeji Italy 28.6(Miliọnu mejidinlọgbọn naira)
Ẹkẹta Amẹrika 27.6(Miliọnu mẹtadinlọgbọn o le diẹ naira)
Ẹkẹrin Singapore 24.2(Miliọnu mẹrinlelogun o le diẹ naira)
Ẹkaarun Japan 23.5(Miliọnu mẹtalelogun abọ naira)
Ẹkẹfa Ilẹ Gẹẹsi 16.6(Miliọnu mẹtadinlogun o din diẹ naira)
Ekeji Kenya 11.8(Miliọnu mejila o din diẹ naira)
Ẹkẹjọ Indonesia 10.3(Miliọnu mẹwa naira o le diẹ naira)
Ẹkẹsan Ghana 7.3(Miliọnu meje o le diẹ naira)
Ẹkẹwa Thailand 6.9(Miliọnu meje o din diẹ naira)

Lati ọwọ iwe atigbadegba: Arabian Journal of Business and Management Review (OMAN Chapter)Vol. 5, No.5; December 2015.

Eyi ti fa ọpọlọpọ awuyewuye laarin awujọ orilẹede Naijiria, paapaajulọ pẹlu bi iroyin se ti nkaakiri ilu saaju asiko yii wi pe awọn asofin Naijiria lo n gba owo to pọ julọ laarin awọn akẹgbẹ wọn lagbaye.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: