Ọlọpa n wa ọkunrin to pa awọn akẹkọ meji nipinlẹ Ogun

Aworan Ada Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lekan Adebisi ni a gbọ wipe o ti na papa bora lẹyin to pa awọn ọmọde meji

Awọn ọlọpa ni ipinlẹ Ogun ti kede wipe awọn n wa afurasi ọdaran ọkunrin kan ti o ṣa awọn ọmọde meji pa nileewe alakọbẹrẹ kani ni ọjọ aje.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpa n'ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ fun ileeṣẹ BBC wipe iṣẹlẹ naa ṣẹ ni ile iwe alakọbẹrẹ ti St. John's Anglican ni Agodo ti o wa ni ijọba ibilẹ Ogun waterside, ti o si kede orukọ awọn ọmọde meji naa gẹgẹ bii Sunday Obituyi ati Mubarak Kalesowo.

Ọgbẹni Oyeyẹmi sọ siwaju wi pe lairo awuyewuye ti o so mọ ọrọ nipa ailera ọkunrin afurasi naa, ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ogun ti n wa a pẹlu ileri wipe wọn yoo faa le awọn dokita lọwọ lati ṣe ayẹwo ọpọlọ fun un ki wọn too da a lẹjọ.

Afurasi apaniyan yi ni iroyin sọ wipe o ṣa deede wọ inu ileewe alakọbẹrẹ yii nigbati awọn ọmọde naa wa ni akoko ijẹun ti o si fi ada ṣa awọn ọmọde meji naa pa nibi ti wọn ti n ṣire.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọlọpa n wa ọkunrin to pa awọn akẹkọ meji nipinlẹ Ogun

Amọṣa, Kọmiṣọna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, arabinrin Modupe Mujọta ti o fi idi iṣẹlẹ yi mulẹ ṣ'alaye pe akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Ogun, Taiwo Adeoluwa ti paṣẹ fun awọn ọlọpa lati wa afurasi yii ri ki o si fi oju wina ọba.

Mujota wipe oun ko lee s'ọrọ lẹkunrẹrẹ nipa iṣẹlẹ yii ayafi ti awọn agbofinro ba pari iwadi lati fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

o ni lasiko naa ni ijọba yoo too le s'ọrọ nipato ohun ti yoo jẹ ṣiṣe.

Afurasi ọdaran naa ti awọn ọlọpa pe orukọ rẹ ni Lekan Adebisi ni a gbọ wipe o ti na papa bora lẹyin ti o d'ẹmi awọn ọmọde meji yi legbodo.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: