Muhammed Alkali; Iléèṣẹ́ ológun ti ri òkú rẹ̀ nínú kànga

Ṣaaju ni ilé-iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pe àwọn rí sàárè tí wọn sin Alkali tó ó sọnù sí lẹ́yìn tí wọ́n paá tán.

Oríṣun àwòrán, Ikechukwu Oha

Àkọlé àwòrán,

Ṣaaju ni ilé-iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pe àwọn rí sàárè tí wọn sin Alkali tó ó sọnù sí lẹ́yìn tí wọ́n paá tán.

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti ri oku Ọgagunfẹhinti, Muhammed Alkali, ti wọn n wa, ni abule Guchwet nipinlẹ Plateau.

Wọn ri iyoku ara rẹ ninu alopati kọnga kan ni abule ọhun to wa ni agbegbe Shen, ijọba ibilẹ Guusu Jos.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti wọn ṣe awari rẹ, Oludari bareke ologun kẹta, Ọgagun Umar Mohammed sọ pe ọkan lara awọn afurasi to jọwọ ara rẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin ti wọn kede pe wọn n wa wọn, lo mu awọn ọmọ ogun lọ si ibi kanga alopati naa.

Oríṣun àwòrán, Ikechukwu Oha

Ṣaaju ni ilé-iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pe àwọn rí sàárè tí wọn sin Alkali tó ó sọnù sí lẹ́yìn tí wọ́n paá tán.

Wọn ni iwadi fihan wi pe saare yi ni awọn afunrasi kọkọ sin ọ̀gágun Muhammed si ki wọn to wu oku rẹ lo si ibomiran.

Ọrọ yi jẹyọ nigba ti ile ise ọmọogun n ba awọn akoroyin sọrọ.

Ilé-iṣẹ́ ọmọogun ni sùgbọn o, àwọn ti mú àwọn afura sí kàn ti wọn lérò pé o lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà látari àwọn ìròyìn to tẹ àwọn lọ́wọ́.

Ọ̀gágun B.A Akinruluyọ tó wà ní Bárékè Rukuba sàlàyé bí wọn ṣe rí sààré náà pẹ̀lú ìrànwọ àwọn ajá ọlọpa tí maa ń fimu fílẹ̀

Ibi ti wọn ti rí sààré náà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ kò ju kìlómítà kan lo sí etí títì márosẹ̀ ní ibi tí wọn ti rí sàárè rẹ̀

Alkali ní olúdarí àti alábojúto àwọn osíṣẹ̀ ní ilé iṣẹ́ ọmọogun. Wọn bẹ̀rẹ̀ sí ni wáa láti ọjọ́ kẹ́ta oṣù kẹ́sàn nígbà tó ń rìnrìn àjò láti Abuja lọ si Bauchi

#JosPond: 'Ọkọ̀ mẹ́ta péré la rí nínú odò adágún'

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian army

Àkọlé àwòrán,

ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ tí wọ́n rí nínú odò adágún

Ile isẹ ologun ori-ilẹ lorilẹede Naijiria ti kede pe ọwọ ti ba ọgbọn afurasi ti wọn mọ nipa ọga ologun to ti fẹyinti Idris Alkali nilu Jos.

Ile iṣẹ ologun sọ pe ajagun fẹyinti naa ko tii di riri lẹyin ti wa inu odo adagun kan ti wọn lero pe ibẹ ni wọn ju ọga ologun naa si, ṣugbọn ọkọ mẹta ni wọn ko jade lati inu odo naa.

Ile iṣẹ ologun ni Ipinlẹ Plateau tun fi lede pe kosi otitọ kankan ninu iroyin ti awọn kan n gbe kiri lori ayelujara pe ọkọ mọkanla ati oku eeyan meji ni awọn yọ jade ninu adgun odo ọhun.

Olori ile iṣẹ ologun lorilẹede Naijiria Lt. General Tukur Yusufu Buratai ti paṣẹ tẹlẹ fun awọn ologun lati wa ọgagun naa ri ni kiakia atoku ataye rẹ.

Egbinrin ọtẹ lawọn isẹlẹ to n waye nipinlẹ Plateau nitori baa se npakan, ni omiran nru.

Akọtun ikọlu miran tun ti bẹ silẹ nipinlẹ Jos ni ipinlẹ Plateau, eyi taa gbọ pe ko sẹyin isẹ ọwọ awọn Fulani darandaran.

Iroyin naa ni ko din ni eeyan mẹẹdogun to jẹpe Ọlọrun nigba ti awọn gende agbebọn to wọ asọ ologun ya bo awọn ilegbe kan lopopona Rukuba, to wa nijọba ibilẹ ariwa Jos, eyi ti ko jinna si ileesẹ ọwọ kẹta awọn ologun orilẹ-ede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

NLC: Àwọn olósèlú ń la títì láì sanwó osù torí owó tí wọn yóò rí lórí àkànse isẹ́

A gbọ pe awọn eeyan kan ti wọn furasi bii darandaran lo ya bo adugbo naa ni oru mọjumọ ọjọ Ẹti, lasiko tawọn eeyan naa n sun lọwọ.

Amọ kaka kewe agbọn dẹ lori isẹlẹ naa, n se lo tun n le koko sii, nitori bi ilẹ ọjọ Ẹti se mọ, lawọn ọdọ ya bo oju popo nigba ti ọkan lara wọn ni oun da sọja kan, to wa lẹnu iloro awọn ologun mọ, gẹgẹ bii ọkan lara awọn to wa se ikọlu ni oru mọju.

Oríṣun àwòrán, JustNnaemeka

Igbẹ aa fẹwe, awọn ọdọ gba agbo sori, ka si to sẹju pẹ, marun ninu wọn tun ti dagbere faye latọwọ awọn sọja, ti ọpọ wọn si ti farapa.

Ni bayii na, ijọba ipinlẹ Plateau ti kede pe ki onile o gbele lawọn adugbo ti rogbodiyan naa ti waye.

Ikọlu mii tun mu ẹmi eeyan mẹẹdọgbọn lọ

Idi ni pe ẹmi eeyan mẹẹdọgbọn mii lo tun bọ nibi akọtun ikọlu to tun waye laarọ ọjọ aje eyi to tun da eto isinku apapọ fawọn eeyan tawọn Fulani darandaran pa ru.

Ọjọbọ ni wọn gbẹmi awọn eeyan ti wọn fẹ sin papọ naa, ti aarẹ Muhammadu Buhari si sẹsẹ se abẹwo ibanikẹdun sipinlẹ naa lọjọ aiku.

Lasiko ikọlu ọtun yii, to sẹlẹ laago meje irọlẹ ọjọ aje, ile mọkanla ni wọn jo kanlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ẹmi lo ti sun ninu ikọlu awọn darandaran nipinlẹ Plateau

Iroyin naa ni awọn Fulani darandaran ni wọn fura si pe o gbẹmi awọn eeyan mẹẹdọgbọn naa, to fi mọ awọn ọmọde mẹta ati obinrin meji ni abule Dundu nijọba ibilẹ Bassa.

Gẹgẹ bi ẹnikan tisẹlẹ naa soju rẹ ti wi, " Ohunto bani ninujẹ pupọ ni isẹlẹ yii nitori a sẹsẹ n palẹmọ lati sin awọn oku ti wọn kọkọ pa ni. Titi di akoko yii, eeyan bii ẹẹdẹgbẹta lo wa nibudo awọn eeyan ti ko nile lori, a si nrawọ ẹbẹ si awujọ agbaye lati wa seranwọ fun wa."

Bakanaa ni agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Plateau, Mattias Tyopev, fidi isẹlẹ yii mulẹ amọ to ni, ko tii si ẹkunrẹrẹ iroyin nipa isẹlẹ yii.