Eko: Awọn Babalọmọ yoo maa gba isinmi ọsẹ meji

Obinrin to sẹsẹ bimọ ati ọmọ tuntun ti wọn sun sori ibusun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akoko isinmi fawọn iyalọmọ ti fo fẹrẹ lati osu mẹta si osu mẹfa nipinlẹ Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti fọwọsi pe ki awọn baba to ba sẹsẹ bimọ tuntun maa lọ fun isinmi ọjọ mẹwa eyi to wa lati sewuri fun asa jijẹ obi rere laari awọn osisẹ ipilẹ Eko.

Bakannaa ni afikun de ba akoko tawọn iyalọmọ yoo maa lo nile fun isinmi eyi to ti fo soke lati osu mẹta si osu mẹfa,

Sugbọn isinmi fawọn babalọmọ ati iya lọmọ yii lo wa fun awọn to ba nbimọ akọkọ ati ikeji.

Akoko isinmi fawọn babalọmọ ati iyalọmọ yii ni wọn ni yoo fun wọn lanfaani lati gbajumọ itọju awọn ọmọ tuntun jojolo wọn, ti yoo si tun rọrun fawọn iyalọmọ lati fawọn ọmọ ni omi ọyan nikan fun osu mẹfa akọkọ.

Ko tan sibẹ o, akoko isinmi yii ni yoo tun jẹ kawọn iyalọmọ raye sinmi lati tọju ara wọn lẹyin ibimọ ko to di pe wọn tun wọ isẹ pada.