Lori ipaniyan Benue: Buhari ṣe'pade pẹlu Ibrahim Idris

Aarẹ Buhari ati Ibrahim Idris Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Buhari ṣe'pade pẹlu ọga ọlọpa

Aarẹ Buhari ti ransẹ pe ọga agba ọlọpa lorilẹede naijiria, Ibrahim Idris lati wa ṣalaye ara rẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o kọ ipakọ si aṣẹ ti aarẹ pa fun lati duro si ipinlẹ Benue.

Ipade pajawiri naa waye nilu Abuja lọjọ iṣẹgun laarin ọgbọn iṣẹju.

Idris ko ba awọn oniroyin s'ọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ.

Agbẹnusọ fun aarẹ Garba Shehu fidi ipade naa mulẹ ṣugbọn ko ṣalaye ohun ti wn sọ nibẹ.

Bakannaa ni aarẹ tun ti gbe aṣẹ kalẹ lati ṣe iwadi to kuna lori iwa ati isẹ awọn ọlọpa lawọn ipinlẹ ti ikọlu ti n waye lorilẹede Naijiria lẹyin eyi ti igbesẹ to loorin yoo waye latọdọ aarẹ.

Image copyright @NG_Police
Àkọlé àwòrán Idris ko ba awọn oniroyin s'ọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ

Ọjọ aje lakara tu s'epo fun ọga ọlọpa idris nigba tawọn eeyan ipinlẹ Benue ke ibosi sita fun aarẹ lasiko abẹwo rẹ si ipinlẹ naa wi pe ọga ọlọpa Idris o duro sibẹ lati dari igbesẹ idojukọ awọn darandaran fulani ti o n da awọn eeyan ipinlẹ ọhun laamu.

Ileesẹ aarẹ lorilẹede Naijiria sọ wi pe gbogbo ọna ni wọn yoo yẹ lati rii daju pe awọn amokunsika to wa nidi ikọlu ati ipaniyan kaakiri orilẹede Naijiria f'oju wi ina ofin.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: