Atunto nbọ nileeṣẹ to n ṣ'akoso eto idariji f'awọn ọdọ agbebọn

Awon agbebọn Niger Delta kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Atunto nbọ nileeṣẹ to n ṣ'akoso eto idariji f'awọn ọdọ agbebọn

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun alamojuto agba fun eto aabo lorilẹede yii lati bẹrẹ iwadi to kuna lori isẹ ileeṣẹ eto aforiji f'awọn agbebọn Niger Delta bẹrẹ lati ọdun 2015 si asiko yii.

Aarẹ Buhari ni ki iwadi naa o gbajumọ ẹsun ikowojẹ ati iwa jẹgudujẹra to n waye nileeṣẹ naa.

Lọjọ iṣẹgun ni aarẹ Buhari yọ Ọgagunfẹyin paul Boroh kuro nipo oludari agba ileeṣẹ naa ti o si yan Ọjọgbọn Charles Quaker Dokubo rọpo rẹ.

Ileeṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria ṣ'alaye wi pe gbogbo iwa ibajẹ to n jẹyọ nileeṣẹ to n ṣ'akoso eto aforiji f'awọn agbebọn Niger Delta to gbe ibọn silẹ fun alaafia lati jọba lagbegbe naa.

Iṣejọba aarẹ Yar'Adua lo gbe ileeṣẹ yii kalẹ lati mojuto wahala to n waye lẹkun Niger Delta ki wọn si ṣeto ati fidi alaafia mulẹ nibẹ.

Ileeṣẹ to n ṣ'akoso eto aforiji f'awọn agbebọn Niger Delta to gbe ibọn silẹ fun alaafia lati jọba lagbegbe ti ran ọpọ awọn ọdọ agbebọn lẹkun naa nigbakanri lọ sileewe pada ti awọn miran si ti gba iranwọ fun idokoowo ara wọn.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: