Ajọ NYSC ko awọn agunbanirọ kuro nileewe l'Ọsun

Agunbanirọ kan n fi ọwọ boju Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ NYSC ko ni fi ojuure wo awọn to ba n dun mọhuru mọ awọn agunbanirọ

Ajọ ti o n seto agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC, ti ko awọn agunbanirọ kuro lawọn ileewe girama kan nipinlẹ Ọsun.

Eyi waye pẹlu bi awọn akẹkọ girama ti wọn funrasi pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun se n kọlu awọn agunbanirọ lọpọlọpọ igba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gulegule ẹgbẹ okunkun wọpọ lawọn ileewe girama nipinlẹ Ọsun

Alakoso NYSC naa nipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Emmanuel Attah, salaye nilu Osogbo wi pe pupọ ninu awọn ileesẹ ati ileẹkọ ni ko bikita fun igbayegbadun awọn agunbanirọ to wa ni ikawọ wọn.

Ọgbẹni Attah salaye siwaju sii wi pe gbogbo awọn ileewe ti awọn akẹkọ ẹlẹgbẹ okunkun ti n damu awọn agunbanirọni wọn ti yọ kuro ninu iwe asepọ pẹlu ajọ NYSC nipinlẹ Ọsun.

Image copyright @nysc_ng
Àkọlé àwòrán Ọpọ agunbanirọ lo ti padanu ẹmi wọn nitori abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria

Gulegule ẹgbẹ okunkun wọpọ lawọn ileewe girama nipinlẹ Ọsun eyi ti o ti di ipenija nla f'awọn agbofinro ati ijọba nipinlẹ naa.

"Awọn to ba gba agunbanirọ gbọdọ lee pese fun ile gbigbe, igbayegbadun pẹlu abo nitoripe nigbakugba ti ajọ NYSC ba kẹẹfin pe ẹmi awọn agunbanirọ rẹ wa ninu ewu, nse ni yoo pe wọn pada kuro nibẹ."

Lara awọn ileewe to kede pe awọn akẹkọ to n sẹgbẹ ọkunkun ti ndun mọhurumọhuru ni ileewe girama, Osogbo grammar school.

Related Topics