Rwanda ko faye gba ariwo irun pipe

Mosalasi ni Rwanda Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹ ma logbohungbohun lati pe irun mọ

Ni orilẹede Rwanda, ni agbegbe Nyarugenge, ni ijọba ti fi ofin de lilo gbohungbohun ni awọn mosalasi lasiko irun idaji nitoripe o n fa ariwo.

Ninu atẹjade lati ọwọ akọwe agbegbe naa, ogbẹni Charles Havugimana, o wipe igbese yi waye leyin amojuto ti wn se ni agbegbe naa.

Ni ọjọ kokandinlogun, osu keji ọdun yi ni wọn se amojuto awọn ile ijosin ati mosalasi, eyi to o fihan pe awọn mosalasi to gbe gbohungbohun si ori orule wọn ma n fa ariwo.

"Mo kowe si yin lati dẹkun ati ma lo gbohungbohun, ki ẹ si wa ọna miran lati maa kesi awọn ọmọ leyin yin, fun irun,'' gẹgẹ bi atẹjade na ti sọ.

Laipe yi, ẹẹdẹgbẹrin sọọsi ni ijọba tipa nitori wipe wọn kuna lati tẹlẹ ofin to rọ mọ ile kikọ ati fun ariwo pipa lorilẹede naa.