Ijamba ọkọ-ofurufu ologun pa 'yan mẹjọ

Ijamba baalu to sẹlẹ lorilẹede naa ni ọdun 1992 pa eeyan mẹrinlelogun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ijamba baalu to sẹlẹ lorilẹede naa ni ọdun 1992 pa eeyan mẹrinlelogun

Ijamba baalu ologun kan ti pa eeyan mẹjọ lorilẹede Senegal bẹẹni eeyan mejila miran farapa .

Ijamba baluu naa ṣẹlẹ nilu Missirah, lẹgbẹ ẹnu alaa orilẹede naa pẹlu ariwa orilẹede Gambia.

Ogun eniyan lo wa ninu baluu naa, ilu Dakar ni wọn si morile lati sinku kan nilu Ziguinchor (guusu) lasiko ti ijamba naa sẹlẹ.

Ọkọ ofurufu ọhun gbe oku eeyan nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ijamba baalu to sẹlẹ kẹyin ni orilẹede Senegal ṣẹlẹ l'ọdun 2015, o si ṣe okunfa iku eeyan meje.