Asofin agba: Ileẹjọ tẹ idaduro agbara ẹka ijọba loju

Ọpa asẹ ile asofin agba ati ami idamọ wọn Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ile asofin agba ni o yẹ ki ẹka isejọ̀ba kọọkan maa bọwọ fun ilana iyapa agbara

Ile asofin agba orilẹede Naijiria ti kede ipinnu rẹ lati kọwe si adajọ agba, Walter Onnoghen, lati safihan ero rẹ nipa idajọ t'ileẹjọ giga ijọba apapọ kan gbe kalẹ eyi to fi nmu lọwọ silẹ lati mase da asẹ Aarẹ Muhammadu Buhari kọja lori atunse ofin idibo.

Olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin agba ilẹ wa, Sẹnatọ Godswill Akpabio lo gbe aba yii kalẹ nibi ijoko ile lọjọbọ.

O wa se apejuwe idajọ ileeẹjọ giga naa gẹgẹbii eyi to nsi ofin idaduro agbara laarin ẹka isejọba lo, to si tọkasi abala ikejilelogoji ati ikejilelaadọta iwe ofin ile eyi to ni ileeẹjọ ko lagbara lori ọrọ yii nitori ilana ti wa nilẹ lori rẹ lati tọ.

Bakanna ni olori ọmọ ẹgbẹ oselu to pọ julọ nile asofin agba, Senator Ahmad Lawan naa kin-in lẹyin pe "lootọ ni idaduro agbara nbẹ ni gbogbo ẹka isejọba, bẹẹ si ni ọrọ to wa nilẹ yii ko tii kan kil ile ẹjọ da sii nitori ilana bi ijọba awa ara wa se nsisẹ niyi.

Nigba to nsọ ero rẹ, aarẹ ile asofin agba, sẹnetọ Bukọla Saraki ni ọrọ idaduro agbara laarin ẹka ijọba kan si omii lo ye gbogbo wọn.

"A ni ojuse tiwa bẹẹ naa si ni ẹka eto idajọ ni ojuse tirẹ pẹlu. Gbogbo wa si la gbọdọ sisẹ lati se amusẹ ojuse ti ilu gbe le wa lọwọ. A si kan si ọọfisi adajọ agba ni Naijiria lori ọrọ yii"

Lẹyin eyi ni ile wa pinnu lati kọwe si adajọ agba lori isẹlẹ naa.