Igbeyawo: Idapọ ọgbọn ọdun fori sanpọn

Oruka Igbeyawo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi igbeyawo se ntuka lemọlemọ lode oni ti di ailasọ lọrun paaka, apero fawọn ọmọ eriwo.

Iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan to peju si kootu ibilẹ to wa nilu ikorodu lọjọbọ nigbati igbeyawo ọgbọn ọdun di pẹẹ ntuka nitori ẹsun iwa pansaga.

Ọkunrin kan, Gbeminiyi Adeyinka, tii se ẹni ọdun mejidinlaadọrun (88), lo wọ iyawo rẹ, Sẹkinat, ẹni ọdun marundinlaadọta (55), wa sile ẹjọ pe o to gẹẹ, ibagbepọ oun ati aya oun ko wọ mọ lẹyin ti wọn ti se tọkọ-taya fun odidi ọgbọn ọdun.

Gbeminiyi ni "iwa pansaga iyawo mi ko lodiwọn, bẹẹ ni kii setọju mi, to si maa nsun ti oniruuru ọkunrin kiri."

"O maa ngbami leti, to si tun fẹ pa mi. Kii fun mi ni ounjẹ, emi ko si fẹ tii ku bayi nitori onuruuru ọkunrin lo maa nwa sun ti ninu ile wa. Adajọ, ẹ jọwọ, ẹ tu wa ka."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Sugbọn Sẹkinat ni oun si nifẹ ọkọ oun, bẹẹ ni oun ko fẹ ki igbeyawo naa tuka. O ni oun nbẹ ileẹjọ lati mase ya awọn nitori ọkọ oun ko fi igba kankan ka ọkunrin mọ mi lori.

Iyawo taku pe oun ko fẹ kọ ọkọ oun

"Gbogbo igba ni ọkọ mi maa nfura si irin ẹsẹ mi debi pe o tun ngboorun pata mi nigba kuugba ti mo ba pada de lati ode. Sibẹsibẹ, emi ko setan lati tu igbeyawo mi ka."

Aarẹ ileẹjọ ibilẹ naa, Arabinrin Funmi Adeọla, wa kede pe tọkọ-taya naa ko lee maa gbepọ ni alaafia mọ, nitoripe iwadi ti fihan pe lootọ ni ẹbọ nbẹ lẹru iyawo, to si jẹbi ẹsun ti ọkọ rẹ fi kan-an.