Ikọlu Plateau: Sọja meji ku, oku mẹtalelogun tun sun

Awọn ọmọogun ninu ọkọ akẹru Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ ẹmi sọja lo ti bọ si oniruuru laasigbo to nwaye lorilẹede Naijiria

Awọn ọmọogun meji ti padanu ẹmi wọn nigba ti wọn nlọ lati lọ wa ọna abayọ si ija laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ nipinlẹ Plateau.

Ikọlu sawọn sọja yii waye lasiko kannaa ti ija laarin awọn agbẹ ati darandaran sokunfa iku awọn eniyan mẹẹdọgbọn (25) ni agbegbe yii kannaa.

Akọroyin BBC, Chris Ewokor sọ wipe awọn ọmọogun naa nlọ lati pẹtu saawọ laarin awọn ara agbegbe Miango ati Rafiki nibi tawọn darandaran wa, nigba ti awọn agbebọn se ikọlu si wọn nijọba ibilẹ Bassa nipinlẹ Plateau.

Awọn ọmọogun meji miran tun farapa pẹlu awọn ọlọpa ati ara ilu, ti wọn si dana sun ọpọlọpọ ile lagbegbe naa.

Oku mẹẹdọgbọn mii tun sun ni Plateau

'Ipinlẹ Benue ko fa'gile eto isinku'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Ileesẹ Ọmọogun orilẹede Naijiria ninu atejade kan sọ wipe awọn ri oku eniyan mẹtalelogun ni agbegbe Mararaba Dare nigba ti wọn se ikọlu si wọn ati awọn ara ilu naa.

Nibayii, ijọba ipinlẹ Plateau ti fofin de irinna awọn eniyan, wọn si fi ofin koni ile ogbele lati aarọ titi di aalẹ de agbegbe naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ti a ko ba gbagbe, eniyan marundinlọgbọn lo padanu ẹmi wọn nigba ti ija be silẹ laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ ni ipinlẹ Plateau.