Eeyan mẹrin ku ninu ijamba afara to wo lulẹ ni Florida

Ọkọ kan ha si abẹ awoku afara naa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọkọ mẹjọ lo ha si abẹ afara naa pẹlu awọn eniyan ninu wọn lasiko ti afara naa ja

Ko din ni eeyan mẹrin to ti dagbere faye bayi ninu islẹ ijamba afara to ja nitosi fasiti Florida International University ni Miami gẹgẹ bii awọn alasẹ se sọ.

Awọn ọlọpa ni awọn osisẹ adoola ẹmi si n wa awọn eeyan kaakiri awoku afara naa lati wa awọn eeyan to ha si ẹsẹ afara naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn to fara sese ninu ijamba afara yii ni wọn wa nileewosan bayii

Afara ọhun wo lori opopona marosẹ ti awọn ọkọ ti ko din ni mẹjọ si fara kaasa isẹlẹ naa lalẹ ọjọọbọ

Olori ileesẹ panapana ni agbegbe Miami-Dade, Dave Downey salaye wi pe eeyan mẹrin loun lee fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti jade laye nipasẹ ijamba naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iroyin kan sọ wi pe wakati mẹfa ni wọn fi kọ afara yii lọjọ abamẹta

"Ọrọ yii ko lee yanju ni kiakia. Gbogbo oru lawọn osisẹ adoola ẹmi yoo fi sisẹ, iyẹn ti ko ba tilẹ tun ju bẹẹ lọ."

Ko din ni eeyan mẹwa ti wọn ti wọn n gba itọju nileewosan Kendall Regional Medical Center, gẹgẹbii Dokita Mark McKenney to n mojuto ọrọ isẹ abẹ nileewosan naa se sọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹrin lan alasẹ lee fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti jade laye nipasẹ ijamba naa

Iroyin kan lori ikanni ayelujara fasiti naa ni wakati mẹfa ni wọn fi kọ afara yii sori opopona marosẹ naa.

Gomina ipinlẹ Florida, Rick Scott pẹlu Sẹnatọ Marco Rubio ti de ibi ti ijamba naa lalẹ ọjọọbọ pẹlu ikọ awọn akọsẹmọsẹ lati ajọ abo oju popo lorilẹede Amẹrika.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ trump sakawe ijamba baalu to ja naa gẹgẹbii eyi to bani ninujẹ

Aarẹ Donald Trump ti ilẹ Amẹrika pẹlu sọ lori ikanni twitter rẹ pe ohun n mojuto bi nkan se n lọ nibi isẹlẹ ijamba afara to ja to mu ibanujẹ ọkan wa naa"

Related Topics