Igbeyawo: Ọsinbajo se idana ọmọbinrin rẹ nile ijọba

Dọlapọ Ọsinbajo, Ọkọ iyawo, Oluseun Bakare, Iyawo, Damilọla ati igbakeji aarẹ Yẹmi Ọsinbajo Image copyright Punch Newspaper
Àkọlé àwòrán Ọjọ Satide ni isn idapọ mimọ yoo waye fun tọkọ-taya.

Ile ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni Aso Rock sọkutu wọwọ ni ọjọ ẹti nigbati igbakeji aarẹ Yẹmi Ọsinbajo se idana mọmi-nmọ ọ fun ọmọbinrin rẹ, Damilọla.

Sugbọn wọn ko gba awọn akọroyin laaye lati yọju sibi eto igbalejo to waye lẹyin idana naa ni gbọngan apejẹ to wa ninu ile ijọba nitori pe idile Ọsinbajo ko fẹ pariwo idana ọhun.

Ile Aguda to wa nile ijọba ti Ọsinbajo ngbe ni wọn ti se idana naa fun Damilọla ati ọkọ rẹ, Oluseun Bakare, eyiti awọn gomina kan peju si.

Agogo igbeyawo nlu nile Ọsinbajo

Kano gbalejo igbeyawo ọmọ gomina Ọyọ

Ọjọ Satide ni isin igbeyawo yoo waye nibudo ijọsin National Christian Centre nilu Abuja, ti ayẹyẹ igbalejo yoo si tẹle ni gbọngan apejẹ to wa nile ijọba nilu Abuja.

Related Topics