Ija nilu Eko: Laasigbo bẹ silẹ ni Ọjọta

Ibudokọ kan nilu Eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ isọta to ngbeja ara wọn lo da wahala silẹ

O seese ki ọpọ eeyan fori ko laasigbo to bẹ silẹ nibudokọ Ọjọta nilu Eko lati ọjọbọ si ọjọ ẹti.

A gbọ pe eeyan meji to nja lo fa sababi isẹlẹ yii, tawọn ọmọ isọta kan si ngbeja ikọọkan awọn to nja naa.

Ọpọ alupupu taa mọ si ọkada la gbọ pe wọn bajẹ ninu isẹlẹ yii, ti igboke-gbodo ọkọ si doju de lagbegbe naa to fi mọ eto kata-kara pẹlu.

Amọ sa, iroyin naa ni wọn ti ko awọn agbofinro lọ sibi isẹlẹ naa.

A maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin to wa ya.