Sẹnẹtọ Naijiri kan ti jade l'aye

Sẹnẹtọ Ali Wakil ti di ologbe Image copyright Nigerian Senate
Àkọlé àwòrán Sẹnẹtọ Ali Wakil ti di ologbe

Sẹnatọ to n s'oju aringungun ipinlẹ Bauchi nile igbimọ asofin agba Naijiria ti ṣe alaisi lẹyin aisan rampẹ kan.

Iroyin kan sọ wi pe asofin na subu lulẹ lowurọ ọjọ Abamẹta nile rẹ to wa l'Abuja.

Lẹyin igba to subu ni wọn gbe lọ si ile-iwosan.

Sugbọn ko pe ti wọn gbe de ile-iwosan naa loba dagbere f'aye.

Agbẹnusọ fun ile-asoju-sofin Naijiria, Yakubu Dogara, ti s'apejuwe iku sẹnẹtọ naa gẹgẹ bi nnkan to kọọ lominu.