Jamb ni kawọn akẹkọ duro de esi idanwo wọn

Awọn akẹkọ ileẹkọ girama to n sedanwo Image copyright AFP

Ajọ Jamb to n ṣ'eto wiwọ ile-ẹkọ giga ti kes'awọn akẹkọ ti wọn kọ idanwo rẹ wi pe ki wọn ṣe suuru diẹ k'esi o fi jade.

Agbnusọ fun ajọ naa, Fabian Benjamen, sọ wi pe ajọ naa n gbiyanju lati ri wi pe gbogbo esi idanwo t'awọn eeyan ṣe jade lori opo ayelujara rẹ.

Ninu ọrọ to ba ileese iroyin Naijiria (NAN) sọ, Ọgbẹni Benjamin sọ wi pe awọn esi idanwo kan yoo jade titi ọjọ kọkandinlogun oṣu keta yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdi ti esi idanwo Jamb yoo se pẹ ko to jade

O ṣi ṣe ileri wipe wọn n tin ṣatunṣe lori gbogbo ipenija ẹrọ ti awọn eeyan n ko lori opo ẹrọ ayelujara rẹ l'ọwọ-l'ọwọ bayii.

Awọn kan ninu awọn ti wọn ko idanwo na ti kọkọ sọ wipe awọn ko ri esi idanwo wọn gba.

Wọn pari idanwo naa lọjọ Abamẹta dipo ọjọ Aiku ti wọn fisi tẹlẹ.

Related Topics