Ayẹyẹ igbeyawo melo ni Aarẹ Buhari lọ latigba to ti gori oye?

BVuhari ati igba keji rẹ nibi ayẹyẹ igbeyawo Yẹmi Ọsinbajo

Aarẹ Muhammadu Buhari ti de ibi ayẹyẹ igbeyawo to to marun latigba to ti jawe olubori nibi ibo aarẹ ọdun 2015.

Ni kete ti wọn kede esi ibo ọdun 2015 tan ni aarẹ naa lọ sibi igbeyawo Bello El-Rufai to jẹ ọmọ gomina ipinlẹ, Kaduna, Nasir Ahmad El-Rufai.

Ninu osu kejila ọdun 2016 ni Aarẹ Buhari sin ọmọ rẹ, Zahra, nigba to fi fun Ahmed Indimi.

Ogunlogo awọn oloselu lo pe si mọṣalaṣi nla to wa l'Abuja ati ile ijọba nibi igbeyawo ọhun.

Lẹyin igba naa, Aarẹ, Buhari ati awọn gomina mejilelogun (22) ni wọn pe sibi igbeyawo ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ ati tipinlẹ Kano ninu osu kẹta.

Àkọlé àwòrán,

Buhari ati awọn gomina mejilelogun (22) ni wọn pe sibi igbeyawo ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ ati tipinlẹ Kano ninu osu kẹta

Nibi igbewo yi Buhari lo se asoju ọkọ iyawo, Idris Ajimobi, to si san owo ori fun Asiwaju Bọla Tinubu, to ṣe asoju iyawo, Fatima Umar Ganduje.

Nigba ti ẹni to lowo ju l'Afrika, Dangote fẹ f'ọmọ rẹ l'ọkọ, Aarẹ Buhari lo ṣe asoju iyawo, to si gba owo ori lọwọ asoju ọkọ iyawo l'ọjọ Ẹti (Friday).

L'ọjọ naa ni Aarẹ Buhari pada sile ijọba nibi ti wọn ti bẹrẹ ayẹyẹ igbeyawo Damilọla Ọsinbajo, to jẹ ọmọ igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo.

T'ẹrin t'ayọ ni Aarẹ Buhari fi ba t'ọkọ t'aya ya aworan pẹlu awọn obi wọn.