Ijamba ọkọ: Ẹmi 18 bọ ni marosẹ Ibadan si Eko

Ijamba ọkọ kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Taya ọkọ kan to fọ lori ere lo fa sabi ijamba ọkọ naa

Eeyan mejidinlogun la gbọ pe o padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to waye lagbegbe adugbo Alapako si Ogunmakin ni opopona marosẹ Ibadan silu Eko.

Awọn eeyan to fori sọta ijamba naa la gbọ pe wọn nrinrin ajo lọ silu Eko ninu ọkọ bọọsi akero kan ti nọmba rẹ jẹ KJA278DS nigbati wọn lọ fori sọ ọkọ ayọkẹlẹ jiipu Ford Explorer kan ti nọmba rẹ jẹ GGE 873XU eyi to nbọ lọna keji.

Ni ọkan lara awọn agbegbe ti awọn agbasẹse to nsatunse oju ọna marosẹ naa ti gbe ọna naa gba oju kansoso nitori isẹ atunse to nlọ lọwọ ni ijamba yii ti waye.

Nigba to nfidi isẹlẹ naa mulẹ, oludari agba fun ajọ ẹsọ oju popo nipinlẹ Ogun, Clement Ọladele ni ẹmi meje lo bọ ninu isẹlẹ naa nigbati eeyan mejila si farapa .

"Taya moto to fọ lojiji lo sokunfa ijamba ọkọ naa, ti wọn si ti gbe oku awọn eeyan to lugbadi ijamba naa lọ si ibudo igbokusi aladani kan to wa ni ilu Isara Rẹmọ."