Ijọba Zimbabwe gbe orukọ awọn to kowo ilu pamọ jade

Aworan Aare Mnangagwa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Emmerson Mnangagwa fi anfaani osu mẹta sile fun awọn ile isẹ ati ọlọdani to ba fe da owo ti wọn ko pamọ pada.

Ijọba orilẹẹde Zimbabwe ti kede orukọ ogunlọgo ile isẹ ti wọn kọ lati da owo ti wọn ko pamọ si ile okere pada.

Losu kọkanla ọdun to kọja ni Aarẹ Emmerson Mnangagwa fi anfaani osu mẹta silẹ fun awọn ile isẹ ati aladani to ba fẹ da owo ti wọn ko pamọ pada.

O sọ wipe owo to to ẹgbeta miliọnu dọla ni wọn ti da pada sugbọn ilọpo rẹ lọna meji si wa ni ile ifowopamọ ilẹ okere.

Yatọ si awọn ti wọn n sisẹ ni ẹka ọgbin ati iwakusa, ọpọ awọn ile isẹ ti awọn ọmọ ilẹ China da silẹ ni wọn fẹsun kan wi pe wọn tapa s'ofin to de isuna lorilẹẹde Zimbabwe.