Dapchi: Ẹgbẹ kan to so pọ mọ IS lo wa nidi ijinigbe awọn akẹkọ

Aworan ajuwe Naijiria
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ kan to so pọ mọ IS lo wa nidi ijinigbe awọn akẹkọ

Abọ iwadi tuntun kan latọwọ ileeṣẹ iroyin kan lorilẹede Amẹrica, Wall Street Journal (WSJ), ti ni o dabi ẹ ni pe igun kan to yapa ninu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram lo wa nidi bi wọn se ji ọgọrun le mẹwa awọn akẹkọbinrin gbe nilu Dapchi, nipinlẹ Yobe, lapa ila oorun ariwa Naijiria loṣu to kọja.

Olori ileeṣẹ iroyin naa n fi iroyin nipa abọ iwadi naa sita leralera loju opo ikansiraẹni Twitter.

O jabọ iroyin pe, ọmọ oludasilẹ ẹgbẹ Boko Haram, Muhammad Yusuf, Abu Musab al-Barnawi ni olori ẹgbẹ naa to so pọ mọ IS.

Iwe iroyin WSJ ni olori ikọ IS l'agbaye, Abu Bakr al-Baghdadi n dẹyẹ si olori ẹgbẹ Boko Haram, Abubakar Shekau.

Dapchi: Naijiria yoo dunadura pẹlu Boko Haram

Awọn olori ileesẹ aabo tẹdo si Dapchi

Iroyin naa ni irinwo ajijagbara lati inu ẹgbẹ mejeeji lo ku ninu oṣu Kẹjọ 2016 lasiko ti ẹgbẹ mejeeji wọya ija.

Bakanna ni iroyin naa fi idi rẹ mulẹ pe iduna-dura ti n lọ nikọkọ lori ati da awọn ọmọbinrin Dapchi naa pada.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni oun yoo duna-dura pẹlu awọn ajinigbe naa lati le gba awọn akẹkọbinrin naa pada.