BBC: Osisẹ ijọba Eko fi tipa gba irinsẹ akọroyin wa

Ohun eelo ayaworan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aimọye igba ni awọn akọroyin maa nkoju abuku lẹnu isẹ wọn

Ileesẹ ọrọ ayika nipinlẹ Eko ti fi tipa tikuuku gba awọn irinsẹ agbohun ati aworan silẹ to jẹ tileesẹ wa BBC, ti wọn si pa gbogbo awọn fidio ati aworan mii to wa lori ẹrọ wa naa rẹ, ti wọn si tun ko wọn lọ.

Awọn osisẹ ileesẹ ọrọ ayika nipinlẹ Eko naa ya bo ibudo idalẹsi to wa ni Olusosun ladugbo Ọjọta nipinlẹ Eko, lati wa mu asẹ ijọba sẹ pe ki wọn ti ibudo atọkọse to wa nibudo idalẹsi naa pa.

Amọ nse ni wọn fi tipa gba awọn ohun eelo isẹ osisẹ akọroyin agba fun ileesẹ BBC, Joshua Ajayi to wa nibudo naa lati sisẹ tiẹ lasiko ti awọn osisẹ ọhun wa nibẹ, to si fẹ seto ifọrọwanilẹnuwo fawọn osisẹ atọkọse ati ontaja ti wọn wa ni agbegbe yii, ti ọrọ naa kan.

Ikọ awọn osisẹ ọba naa, ti Oludari kan nileesẹ ọrọ ayika, Awoniyi Joshua ko sodi, lo pasẹ pe ki wọn ti ibudo atọkọse naa pa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ijọba fẹ le wa kuro ni Ọjọta'

Koda, ko tiẹ naani igbe ati ẹkun awọn to ni sọọbu nibudo naa, ti wọn n bẹbẹ pe ki ijọba tubọ fun awọn ni akoko diẹ sii lati ko awọn ọkọ awọn onibara awọn kuro nibudo naa, bẹẹ ni ọpọ wọn ntiraka lati wa tabi wọ awọn ọkọ naa jade.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ọpẹlọpẹ Oludamọran si gomina feto iroyin, Idowu Ajanaku, to dasi ọrọ naa lo mu ki Akọwe agba fun ileesẹ ọrọ ayika ko awọn irinsẹ akọroyin agba wa silẹ.

Bakanaa ni jẹbẹtẹ gbọmọ lee lọwọ lai lee salaye idi to fi fi tipa tikuuku gba awọn irinsẹ osisẹ BBC naa, to si tun fi tipa wọle sori awọn irinsẹ naa ati idi to fi pa awọn fidio ati ohun to wa lori ẹrọ agbohun ati aworan silẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIna: Ibudo idalẹsi Olusosun-Ọjọta njona

Nibayi, gbogbo aayan ileesẹ wa lati gbọ ti ẹnu ijọba ipinlẹ Eko ni ko si so eso rere.

A maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin ni kete tijọba ipinlẹ Eko ba ti tan sọ ero ọkan rẹ nipa isẹlẹ yii.