Fayose ni awọn to dibo fun Buhari nilo aforiji Ọlọrun

Fayose n ba awọn eeyan kan sọrọ
Àkọlé àwòrán,

Gomina Fayose ni awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti fi ara han gẹgẹbi awọn eeyan to lẹnu ninu isejọba wọn

Gomina Ayọdele Fayose tipinlẹ Ekiti ti sọ wi pe gbogbo awọn eeyan to dibo fun aarẹ to wa lori oye bayii lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lasiko idibo apapọ ọdun 2015, lo yẹ ko lọ tọrọ aforiji Ọlọrun nitoripe "awọn gan-an lo sokunfa wahala ọrọ aje ati aisi aabo to daju bawọn ọmọ orilẹede Naijiria."

Nile ijọba ipinlẹ Ekiti to wa nilu Ado Ekiti ni gomina Ayọdele Fayose ti sọ ọrọ yii.

Bakannaa ni Fayose tun bu ẹnu atẹ lu gomina ana nipinlẹ naa, Dokita Kayọde Fayẹmi wi pe ko sa ipa gbogbo to to lati sawari awọn ohun alumọni ilẹ to gunwa sipinlẹ Ekiti.

Àkọlé àwòrán,

Fayose jẹ asiwaju gboogi laarin awọn alatako ijọba to wa lode bayii lorilẹede Naijiria

"Aimọye ohun alumọni lo wa nipinlẹ Ekiti, sugbọn aarẹ Buhari lọ n na ogoji biliọnu naira fi nwa epo rọbi lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, kinni Fayẹmi n se lati sawari awọn alumọni ipinlẹ yii ?"

Gomina ipinlẹ Ekiti ni ohun to n sẹlẹ nipinlẹ Ekiti to fi dabi ẹni wi pe awọn Ekiti ko fara mọ nkan ti Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ oselu APC n fọn sita fun awọn omo orilẹede Naijiria ni wi pe, awọn araalu ti fi han nipinlẹ naa pe ohun araalu, ni ohun Ọlọrun.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O wa rọ awọn osisẹ nipinlẹ Ekiti lati tete lọ gba kaadi idibo wọn ni imurasilẹ fun eto idibo ọdun 2018 ati 2019.

Losu keje ọdun 2018 ni eto idibo sipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Ekiti lẹyin ti saa keji isejọba gomina Ayọdele Fayose ba pari.