Boko Haram: Ọwọ agbofinro tẹ Jonah to n ta ibọn fun wọn

Awọn ologun Naijiria pẹlu ibọn ati ọta ibọn Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ẹmi ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bọ nitori ikọlu Boko Haram, awọn ajinigbe ati ajijagbara

Ọwọ awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria ti tẹ okunrin kan to n sowo ibọn oloro, ẹni tawọn agbofinro ti n wa fun bii ọdun mẹwa.

Afunrasi naa lo n ta ibọn fun awọn ikọ agbebọn kaakiri Naijiria.

Wọn fi ẹsun kan afunrasi naa wi pe o n ta ibọn atawọn ohun ija oloro gbogbo fun awọn ikọ agbebọn gbogbo kaakiri orilẹede Naijiria.

Oniruru awọn eeyan ni wọn ti di ero ọrun lati ipasẹ awọn wahala ati rogbodiyan kaakiri orilẹede Naijiria.

Eyi seese ko jẹ ọna abayọ kan gboogi, lọna ati se awari bi awọn ohun ija se n de ọwọ awọn ikọ agbebọn ati alakatakiti gbogbo lorilẹede Naijiria.

Awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ ni afurasi naa, Jonah Abbey lo n ko ohun ija oloro fun awọn ẹgbẹ agbebọn kaakiri Naijiria, paapaa julọ lẹkun Niger Delta, ila oorun gusu ati awọn agbegbe kan lẹkun aringbungbun orilẹede Naijiria.

Image copyright Nigeria presidency
Àkọlé àwòrán Lẹyin ọdun mẹwa, ọwọ awọn agbofinro tẹ afunrasi ọdaran to n ta ibọn fawọn agbebọn

Laipẹ yii lawọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ tọpinpin awọn ohun ija oloro kan lati ilu Konduga nipinlẹ Borno, nibi ti awọn agbebọn Boko Haram ti n sọsẹ, lọ sipinlẹ Taraba nibiti wahala darandaran Fulani ati awọn agbẹ ti nbawọn finra.

Afurasi naa pẹlu awakọ rẹ, Agyo Saviour ni ọwọ awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ tẹ.

Fun ọdun mẹwa ni awọn agbofinro fi n wa arakunrin jonah Abey pe o lọwọ ninu okoowo ibọn ati ohun ija oloro.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Gẹgẹbii awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ se sọ, lati orilẹede Cameroon ati apa ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ni ọgbẹni Jonah Abbey ti n ko awọn ohun ija oloro yii wọle.

Afunrasi naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun o, sugbọn awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ ni, yoo fi oju ba ile ẹjọ laipẹ.