Dapchi:Amnesty International ni ile isẹ ologun Naijiria kọti ikun si ikilọ

Okan lara awọn obi awọn omo ti won jigbe ni Dapchi Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awon obi n beree omo won lowo ijoba

Ajọ ton ja fun ẹto ọmọniyan lagbaye, Amnesty International,ni ile ise ologun lorileede Naijiria koti ikun si ọpọ ikilọ saaju ki ikọ Boko Haram to ji awọn akẹkọ Dapchi gbe.

Wọn ni awọn asaju lawujọ mẹtalelogun ọtọọto lawọn ba sọrọ ti won si ni awọn ri awọn agbesunmọmi naa lagbegbe awọn lọjọ ti ikọlu naa sẹlẹ.

Oniroyin wa Stephanie Hegarty ni gẹgẹ bi iwadi Amnesty ti se se afihan,ọpọ awọn asaju ilu pe akiyẹsi awọn ọmọ ogun si pipejọ awọn agbesunmọmi labule kan ti orukọ rẹ njẹ Gumsa eyi to wa ni iwọn kilomita mẹẹdọgbọn si Dapchi.

Amnesty International ni koda wọn fi to awọn ọmọ ogun leti bi ikọlu naa ti se'n waye sugbọn wọn ko lati gbe igbese kankan.

Agbẹnusọ ile isẹ ologun ni ijọba ti se agbekale igbimo kan ti yoo se iwadi lori aisedede nipa abo eleyi ti o se okunfa jijigbe awọn akẹko naa.

Ninu atejade kan ti wọn fi sọwọ lọse kan lẹyin isele naa,ile ise ologun gba pe looto ni awọn ọmọ ogun sidi kuro ni Dapchi saaju ijinigbe naa.

Ohun ti wọn so ni pe ko si ifoya lori abo Dapchi ati pe agbegbe ibomiran nilo awọn ọmọ ogun awọn.