Ọjọ idunnu lagbaye: Ipo karun ni Naijiria wa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini ohun to'n mu idunu ba ọkan re?

Orileede Naijiria se ipo karun ninu iwadi ọlọdọdun kan ti wọn maa ngbe jade lori awọn orileede ti inu wọn dun julo ni Afrika.

Ẹka to n risi idagbasoke to peye fun ajọ isọkan orilẹede agbaye ma ngbe iwadi jade niranti ayajọ ọjọ iduunu.

Ninu atejade naa ti won fi sita lojo ojoru, Naijiria goke afara si ipo kokanlelaadorun lagbaye.

Esi iwadi naa a ma se agbeyẹwo awọn osuwọn nnkan ti orileede kookan ni lati mọ odiwọn bi idunnu ti se gbalẹ laarin awọn ọmọ orileede wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ohun to nmu idunnu ba ọkan se otọọto sugbọn iwadi naa lo awọn odiwọn kan lati mọ awọn ohun to maa nmu idunnu ba ọkan awọn eeyan.

Lara rẹ ni iye owo ti enikookan npa wole, bi ẹmi se ngun si, ominira, iranwọ lati ọdọ ijọba ati bi ko se si iwa ibajẹ ni isejọba.

Awon orilẹẹde to saaju lori atẹ odiwọn idunnu.

Finland ni orilẹẹde to gba ipo kinni ninu abo iwadi odun 2018.

Norway to se ipo kinni lodun to koja lo se ipo keji.

Denmark, Iceland ati Switzerland lo tele wọn.

Finland lo si ni awọn atipo ti inu wọn dun julo ninu abọ iwadi ọdun yi.